AWÓ LỌ! WỌ́N DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN ALÁGA ẸGBẸ́ AWAKỌ̀ L'ÈKÒÓ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 25, 2020

AWÓ LỌ! WỌ́N DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN ALÁGA ẸGBẸ́ AWAKỌ̀ L'ÈKÒÓ

Ilé ẹjọ́ gíga ti Ikeja n'ilu Èkó tí dá ẹjọ́ ikú fún alaga ẹgbẹ́ awakọ èrò NURTW, ẹ̀ka ti Boundary/Ayetoro nipinlẹ Eko, Saheed Arogundade lórí ẹ̀sùn pé ó pa ọlọ́pàá kan.

Ọlọpaa náà, Gbenga Oladipupo nii ṣe ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n, nígbà tó ṣe alabapade ikú òjìji náà.

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ, èyí tó gbà wákàtí mẹta gbáko, adájọ́ Olabisi Akinade pàṣẹ pé, nítorí ìpèsè ààbò tó péye, kí wọn tí gbogbo ọ̀nà tó wọ inú gbọ̀ngàn igbejọ náà, kí wọn sì kó àwọn kọ́kọ́rọ́ rẹ wá fún òun, lọ́nà àti dènà kí idaru-dapọ má bàa wáyé lásìkò tí igbejọ bá ń lọ lọ́wọ́.

Nínú àlàyé rẹ, aṣáájú ikọ olupẹjọ, Arábìnrin C Rotimi-Odutola ṣàlàyé fun ilé ẹjọ́ pé ọ̀daràn náà ṣẹ ẹsẹ ọhun lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kẹrin ni ìkòríta Gbara, Ayetoro ládùúgbò Ajegunle nílùú Eko.

"Olóògbé náà ń wà ọkada lọ láti ṣe abẹwo si màmá rẹ, Arábìnrin Mojisola Martins ni ile rẹ to wá ní òpópónà Olayinka ni Ajegunle, nígbà tí àwọn gende mẹ́rin ṣẹburu rẹ nikorita Gbàrà, àwọn mẹta nínú wọn mú Ọlọpaa náà mọ́lẹ̀, tí Arogundade sì ń gùn olóògbé náà laimọye ìgbà, kí gbogbo wọn to salọ."

"Wọn gbe olóògbé tó fara gba ọgbẹ náà lọ sílè ìwòsàn àmọ́ ẹpa kò boro mọ, Ọlọpaa náà jáde láyé."

Ikọ olupẹjọ náà ni, ẹsẹ kan ṣoṣo tí olóògbé náà ṣẹ àwọn awakọ èrò náà, tí wọ́n fi rán án sọrun ọsan gangan ni pé, ó sewuri fún àwọn onikẹkẹ Maruwa láti máa na Ayetoro, èyí tó ń mú adinku bá owó tí àwọn awakọ èrò ń pá.

Nínú ìdájọ́ rẹ, adájọ́ ni ikọ olupẹjọ fi ẹri tó dájú hàn pé Arogundade lo gbẹmi Ọlọpaa naa, to sì ni kí wọn yẹ igi fún un, títí tí ẹ̀mí yóò fi bọ lára rẹ.

Àmọ́ Adájọ́ Akinlade fún àwọn olujẹjọ márùn-ún yòókù tó ń jẹjọ pẹ̀lú Arogundade ni ìdáǹdè lórí ẹ̀sùn onikoko méjì, tí wọn fi kan wọn.

Ní kété tí adájọ́ gbé ìdájọ́ rẹ kalẹ tán, ní Arogundade ṣubú lulẹ nílé ẹjọ́, táwọn mọlẹbi rẹ náà sì bu sí ẹkún kíkorò.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI