Ọ̀RỌ̀ ŃLÁ! BAÁLÉ ILÉ TÓ FIPÁ BÁ ÌYÀWÓ RẸ̀ LAṢEPỌ TÓ FI KÚ D'ÈRÒ ÀTÌMỌ́LÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 25, 2020

Ọ̀RỌ̀ ŃLÁ! BAÁLÉ ILÉ TÓ FIPÁ BÁ ÌYÀWÓ RẸ̀ LAṢEPỌ TÓ FI KÚ D'ÈRÒ ÀTÌMỌ́LÉ


Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó fipá bá ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, tí obìnrin náà sì gbabẹ̀ kú
Awọn agbofinro ti mu afurasi kan lori ẹsun wi pe o fipa ba iyawo rẹ lopọ ti obinrin naa si gba ibẹ dreo ọrun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Jigawa, Abdu Jinjiri ṣalaye pe abule Kankaleru ni ijọba ibilẹ Ringim ni iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa, Alasan Audu fipa ba iyawo rẹ lopọ lẹyin ti obinrin naa kọ lati fun un.

Ọgbẹni Abdu Jinjiri fikun ọrọ rẹ pe awọn tọkọ taya naa ti n ni ede-ai-yede tẹlẹ ti wọn fẹ ara wọn fun ogunjo pere ki ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni iyawo naa to di oloogbe, ẹni ọdun metadinlogun ko fẹ fẹ ọkunrin naa lọkọ, ṣugbọn wọn mu ni tipa tipa lati fẹ ẹ.

Iwadii awọn ọlọpaa fihan pe laago mẹrin oru ni ọkunrin naa wọle tọ iyawo rẹ lọ, ṣugbọn obinrin naa ko gba lati jọ ni ajọṣepọ pẹlu ọkọ rẹ nitori oun kọ lo wu u lati fẹ.

Bayii ni atẹjade ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa fipa ba iyawo rẹ lopọ lati le tan ifẹ inu ara rẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI