AYÉ Ó! ÀWỌN ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ỌBA OLUWO TÚN TU SÍTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 20, 2020

AYÉ Ó! ÀWỌN ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ỌBA OLUWO TÚN TU SÍTA


Ọsẹ to kọjá yìí kò fẹ́ ẹ dùn fún ọkàn lára àwọn gbajugbaja Ọba ilẹ̀ Yorùbá nnì, Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi lórí bí olorì rẹ tó kẹru jáde lọdun tó kọjá ṣe tú àwọn àṣírí ńlá nípa rẹ, tó sì tún sọ pé ṣe ni Oluwo fipá bá òun laṣepọ nígbà táwọn kọ́kọ́ mọra.

Olori Oluwo tẹ́lẹ̀, ìyẹn Chanel Chin, ọmọ orílẹ̀-èdè Jamaica tó filu Canada ṣe ibùgbé tú àṣírí náà níbi ifọrọwerọ tó lè ní wákàtí márùn-ún, èyí tí ileeṣẹ tẹlifiṣan GIO ṣe fún un lórí ìkànnì ayélujára tí Fesibuuku.

Ko sẹni tó rí bí Chanel Chin ṣe ń sọ̀rọ̀, tó ń tú àṣírí Oluwo tí kò yà lẹ́nu, nítorí pé kò sẹni tó lérò pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹẹ lè jáde lẹ́nu ẹ. 

Chanel Chin sọ pé "Oṣù kejìlá ọdún 2015 ni mo dé sí orílẹ̀-èdè tí Nàìjíríà pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi kan tòun jẹ́ ọmọ Nàìjíríà. Irin ajo afẹ là ṣe wá nígbà náà, ìlú Èkó là sì dé sí. 

"Oṣù Kínní-in ọdún 2016 ni ọkàn lára àwọn tí a jọ wá nínú ẹgbẹ́ tí a jọ wá sí Nàìjíríà sọ pé wọn fẹẹ ṣayẹyẹ iwuye, àti pé òun máa fẹ ki n wa nibẹ láti mọ bí àṣà àti ìṣe Yorùbá tún ṣe rí. Àwọn tí a jọ wá sọ pé mi ò gbọ́dọ̀ lọ torí pé wọn burú nibẹ àti pé inú igbó.

"O sọ fún mi pé òun kò fẹ́ kó jẹ́ pé Eko ati Lekki nìkan ni máa rí kí n tó padà, àti pé òun tún fẹ ki n ní ìrírí pupọ sì í. Ìdí re e tí a fi lọ síbẹ̀. Ọjọ́ kejì oṣù kejì ọdún 2016 tó jẹ́ oṣù kan gbáko lẹ́yìn iwuye Oluwo ni olólùfẹ́ ọrẹ mi kan mú mi mọ Oluwo n'ilu Eko. 

"Ayẹyẹ kan là tí pàdé ni Ikẹja. Bí a ṣe ṣetan ni mo ti gba yàrá otẹẹli tí mo wà lọ láti sún torí pé ó ti rẹ mi. Aago mẹ́ta òru ni mo làjú, ó jẹ ìyàlẹ́nu fún mi pé Oluwo ni mo bá lẹgbẹ mi nihoho, tó tú tí bọ èmi náà sihoho. Ṣe ni mo pariwo mọ-ọn pé kò dìde kúrò lórí mi. 

"Oluwo ni Ọba lòun, àti pé ẹnikan kii rí ìhòòhò Ọba kò tún kọ ibalopọ. Ó tún ṣèlérí pé òun yoo fi mí ṣe olorì rẹ l'Aafin. Mo ní kó lọ sọ fáwọn èèyàn rẹ pé ṣe lòun fipá bá ní laṣepọ lalẹ ọjọ́ tí a kọkọ pàdé. 

"Oṣù kan lẹ́yìn ẹ ní mo ṣàkíyèsí pé mo ti lóyún. Tí ẹ bá ka oṣù kọkànlá sì oṣù kinni tó bá mi laṣepọ, ẹ máa rí pé oṣù mẹsan ni mo bímọ.

"Bí mo ṣe sọ fún un pé mo ti lóyún lo tí sáré mú mi lọ s'Aafin. Kò sí nnkan to ń jẹ Ààfin, Ààfin to ń lo kò ní òrùlé lórí. Ilé Amofin Atanda là ń sún sì, UK ni ẹni náà ń gbé, ó sì lè jẹri sì ọ̀rọ̀ mi. 

"Ìgbéyàwó mi pẹ̀lú Oluwo jẹ́ kí n ní ọ̀tá rẹpẹtẹ, táwọn kan sì ń pe mi ni èèyàn burúkú. Ọjọ́ tí mo dé Ààfin gan án ní pupọ àwọn obìnrin tí mú mi ni ọta, torí pé pupọ àwọn obìnrin ni Oluwo tí ṣèlérí ìgbéyàwó fún lẹ́yìn tó bá ti fipá bá wọn laṣepọ tán. 

"Mọlẹbi kan wà sì Ààfin lọ́jọ́ kan, nígbà tí wọn gbọ pé akátá ni Oluwo gbé wa s'Aafin. Ó fipá bá ọmọ wọn laṣepọ, Oluwo sì lo ja ibale ẹ, bí wọn ṣe gbọ pé èmi lo fi ṣe Olori ni wọn ti lọ gbé ọ̀rọ̀ náà fáwọn oniroyin.

"Lẹyin yẹn lo tún ń fipá báwọn obìnrin laṣepọ káàkiri, tó sì ń ṣèlérí pé òun yóò fi wọn ṣe Olórí l'Aafin. 

"Nígbà tiroyin náà ti káàkiri gan án wí pé akátá ni Olórí tuntun lo pé àwọn oniroyin láti purọ fún wọn pé ìyàwó tòun fẹ sì Canada lo wá sílè láti ja fún ẹtọ rẹ. Irọ ńlá tó jìnnà sí òtítọ́ ni. 

"Èmi ni obìnrin karùn-ún tó bímọ fún Oluwo, ọmọ tèmi lo sì jẹ ọmọ kẹsàn-án tí Oluwo ni. 

"Nígbà tí mo kúrò l'Aafin ẹ, ó sọ pé iṣẹ aṣẹwo ni mo ń ṣe káàkiri, àti pé èmi ni mo fipá bá òun laṣepọ lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí a pàdé. 

"Ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Ọba yín Oluwo pé kí ló dé tó gbé adé lè mi lórí nígbà tó mọ pe iṣẹ aṣẹwo ni mo ń ṣe. Adé àwọn bàbà-ńlá yín lo gbé lé mi lórí. Ẹ béèrè lọ́wọ́ ẹ pé kí ló dé tó gbé adé iṣẹṣe lè mi lórí nígbà tó mọ pe iṣẹ nọbi ni mo ń ṣe. Ó yẹ kó tí ye e yín pé irọ lo ń pá."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI