ỌPẸ O! NÍTORÍ KONILEGBELE, ÌJỌBA KWARA GBÉ ETO Ẹ̀YÁWÓ KALẸ FÁWỌN ONIMỌTO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 20, 2020

ỌPẸ O! NÍTORÍ KONILEGBELE, ÌJỌBA KWARA GBÉ ETO Ẹ̀YÁWÓ KALẸ FÁWỌN ONIMỌTO


Ṣe ni ìdùnnú ṣubú lu àwọn ará ipinlẹ Kwara, pàápàá àwọn awakọ pátápátá lónìí nígbà tí Gomina ipinlẹ náà, Malaamu AbdulRahman AbdulRazaq bẹ̀rẹ̀ eto ẹyawo fún wọn. 

Àdúrà ńlá-ńlá ni pupọ àwọn tó rí àǹfààní náà jẹ, àtàwọn tó fetí gbọ ọ ń gba fún Gomina AbdulRazaq títí di àsìkò tá a parí ìròyìn yìí. 

Abẹ eto kan tí wọn pé ní Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP) ni ìjọba ipinlẹ náà tí gbé anfaani yìí kalẹ látàrí konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ káàkiri gbogbo Nàìjíríà. 

Lára àwọn erongba ìjọba gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ ni pé àwọn awakọ lo jẹ́ pé owó ojúmọ́ ni wọn fi ń jẹun, tí sì fi ń bọ̀ mọlẹbi wọn. 

Yàtọ̀ sí àwọn tó ń wá mọto, ìyẹn awakọ, àwọn ọlọkada, òní maruwa náà tún pẹ̀lú àwọn tó jẹ àǹfààní yii. 

Nínú ìròyìn mi in là tún ti gbọ pé ìjọba tún nawọ àánú sáwọn èèyàn káàkiri ìjọba ibilẹ tí kò dín ni méjìlá lónìí lórí konilegbele tó lọ láti dẹkùn itankalẹ àrùn COVID-19, ìyẹn Koronafairọọsi. 


Ọjọ́ Àìkú, ìyẹn Sande ana ni pinpin àwọn oúnjẹ náà bẹ̀rẹ̀ káàkiri àwọn ìjọba ibilẹ méjìlá náà. 

Oríṣiríṣi oúnjẹ là gbọ pé ìjọba di sínú àpò ńlá kan, tí wọn sì gbé e fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI