Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ ÌDÍ T'ÀWỌN ỌLỌPAA ṢE FI NAIRA MARLEY ATI OLUDIJE SÍPÒ GÓMÌNÀ L'EKOO SILẸ L'ATIMỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

Ẹ̀KÚNRẸ́RẸ́ ÌDÍ T'ÀWỌN ỌLỌPAA ṢE FI NAIRA MARLEY ATI OLUDIJE SÍPÒ GÓMÌNÀ L'EKOO SILẸ L'ATIMỌLE


Ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Eko ti jẹ́ kó di mimọ pé àwọn tí fi gbajumọ olorin takasufee nnì, Azeez Faṣọla táwọn èèyàn mọ sì Naira Marley àti oludije sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko lọ́dún tó kọjá, Babatunde Gbadamọsi silẹ wí pé kí wọn ṣí máa lọ sílè. 

Beeli là gbọ pé wọn fún àwọn èèyàn náà pẹ̀lú oniduro. Òfin tijọba ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ fáwọn ọlọpaa ni pé wọn kò gbọ́dọ̀ tí ẹni tó bá tàpá sì òfin konilegbele mọle ju wákàtí mejidinlaadọta (48hours). 

Ọjọ́ Tuside àná ni ileeṣẹ ọlọpaa fi àwọn èèyàn náà silẹ. 


AWIKONKO gbọ pé bí wọn ṣe fi wọn silẹ kò sẹyin bí ilé ẹjọ tó yẹ kó gbọ ẹjọ wọn kò ṣe ṣílẹ̀kùn. 

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Bala Elkana lo fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, tó sì ni wọn yóò fojú wọn ba ilé ẹjọ bí ilé ẹjọ náà bá ti ṣílẹ̀kùn padà. 

Òun náà lo sì tún fi ye wá pé yàtọ̀ sí Naira Marley àti Babatunde Gbadamọsi táwọn fi silẹ, àwọn tún ti ẹni kan náà silẹ tí wọn jọ lọ sí ilé Funkẹ Akindele àti ọkọ rẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI