NÍTORÍ KORONAFAIRỌS, ṢỌỌṢI MFM BẸ̀RẸ̀ ÌSÌN L'ORI DSTV ÀTI GOTV - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

NÍTORÍ KORONAFAIRỌS, ṢỌỌṢI MFM BẸ̀RẸ̀ ÌSÌN L'ORI DSTV ÀTI GOTV


Orin ọpẹ làwọn ọmọ ìjọ Orí Òkè Ina àti Iṣẹ Ìyanu, ìyẹn Mountain of Fire and Miracles Ministries (MFM) to jẹ́ ti Dọkita Daniel Kọlawole Olukọya mú sẹnu lọ́jọ́ Tuside àná, nígbà tí ìjọ náà kéde wí pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ ìsìn olojoojumọ báyìí lórí àwọn amohunmaworan tí GOTV àti DSTV.

Irọlẹ àná ni ṣọọṣi MFM kéde ọ̀rọ̀ yìí síta lórí ìkànnì ayélujára tí Fesibuuku. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní gbogbo eto lo tí parí láti bere ìsìn olojoojumọ wọn lórí àwọn ìkànnì lórí ẹ̀rọ amohunmaworan tí ileeṣẹ Multichoice, ìyẹn GOTV àti DSTV. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ti í sọ ìgbà àti àkókò táwọn ìsìn náà yóò máa wáyé, wọn jẹ kò ye wá pé fáwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ìjọ náà lè máa mọ nnkan tó ń lọ lásìkò konilegbele yìí ló jẹ́ káwọn gbé igbesẹ náà. 

Fáwọn to bá mọ ṣọọṣi MFM, wọn a mọ pe orí ìkànnì amohunmaworan tí 'Strong' nìkan ni wọn wá tẹle, tó sì jẹ pe àwọn tó ń lo DSTV àti GOTV kò láǹfààní láti máa mọ nnkan tó ń lọ. 


Ṣùgbọ́n ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ náà tó ti gbọ ni wọn ti ń retí kí àwọn aláṣẹ kéde ìgbà àti àkókò. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI