FLORENCE, ÌYÀWÓ AJIMỌBI TU ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ỌKỌ̀ RẸ SÍTA, Ó LÒ MÁA Ń FI ỌBẸ̀ ẸYIN JẸ ÒUN N'IṢU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 9, 2020

FLORENCE, ÌYÀWÓ AJIMỌBI TU ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ỌKỌ̀ RẸ SÍTA, Ó LÒ MÁA Ń FI ỌBẸ̀ ẸYIN JẸ ÒUN N'IṢU


Ọrọ náà kò jọ ère, bẹ́ẹ̀ ni kò jọ awada rárá nígbàtí ìyàwó Gómìnà àná nipinlẹ Ọ̀yọ́, Abiọla Ajimọbi, ìyẹn Arábìnrin Florence Ajimọbi tú àṣírí ọkọ rẹ síta fún gbogbo ayé, tó sì ń ṣe pupọ àwọn tó gbọ́ ni kayeefi ńlá. 

Ohun tó tún jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yà pupọ àwọn èèyàn lẹ́nu ni pé orí ẹ̀ka ìkànnì ayélujára tí Instagram ni Arábìnrin Florence tí tú àwọn àṣírí síta.

Ki í ṣe pé obìnrin náà dee de tú àṣírí nípa ọkọ rẹ tó jẹ́ tún jé àgbà olóṣèlú, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi síta, bí kò ṣe àwọn ìbéèrè tí ọkàn lára àwọn ọmọ rẹ, ìyẹn Bisọla béèrè lọ́wọ́ rẹ nípa ìgbéyàwó. 

Nínú ifọrọwerọ tí Bisọla ṣe fún màmá rẹ lo tí jẹ́ kó di mimọ pé eemeji ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lòun tí ká Ajimọbi lórí obìnrin méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tó sì ni ṣe lòun tún dariji. 

O ni ọpọ ìgbà ni ọkọ òun ti fi ọbẹ ẹyin jẹ́ òun niṣu, tó sì jẹ pe boun bá ti kà á, ẹ̀bẹ̀ lo máa ń bẹ òun, tí kò sì sí nǹkan tòun fẹ ẹ ṣe ju koun dariji lọ. Ó lòun kii gbé ọ̀rọ̀ náà sọ lẹ́nu mọ tàbí pé koun fi buu, tó sì ni lára nnkan tó ń jẹ ki ìgbéyàwó di ọjọ́ alẹ nìyẹn. 

Nibẹ náà lo tún ti sọ pé òun nígbà tó yá, ṣe lòun rí ọkọ òun gẹ́gẹ́ bí ajẹku oúnjẹ òun, nítorí pé gbogbo èyí tó ní láárí lára rẹ lòun tí gba tán, nítorí náà kò jọ òun lójú tó bá lọ sọ́dọ̀ obìnrin mi-ín.

Florence sọ pé nǹkan tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin kò mọ ni pé bí ọkọ wọn ba n yan àlè, nítorí ibalopọ lásán ni, kí í ṣe nítorí ìfẹ́, àti pé kò sí ọkùnrin tó máa nifẹ obìnrin tó ń yà lale ju ìyàwó rè lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI