GÓMÌNÀ ABIỌDUN, ẸLẸYINJU ÀÁNÚ MẸKUNNU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 19, 2020

GÓMÌNÀ ABIỌDUN, ẸLẸYINJU ÀÁNÚ MẸKUNNU


Bí wọn ba n dárúkọ àwọn Gomina tí ẹmi Ọlọ́run wá lára rẹ, tó sì ń fi ibẹru Ọlọ́run dárí àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò yìí, ọkàn pàtàkì ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun.

Ki í ṣe ahesọ wí pé onigbagbọ, ìyẹn Kristẹni pọnbele ni Gomina Dapọ Abiọdun, tí igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele náà sì jẹ Mùsùlùmí òdodo pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọhun.

Ko si bí ìjọba yóò ti dára to ti ko ni í sì àléébù nibẹ, lára àwọn àléébù yìí làwọn igbimọ, amugbalẹgbẹ, agbẹnusọ àtàwọn aṣojú ipò tó ń bá gomina ṣíṣẹ. Àwọn èèyàn yìí náà wá nínú ìjọba Gomina Dapọ Abiọdun tí wọn kò sì fẹ́ ẹ jẹ ki ìṣẹ Gomina yọ.

Bí ẹ bá fẹ́ ẹ mo bóyá Gomina ẹlẹyinju àánú ni Ọmọba Dapọ Abiọdun tàbí ọdaju ni, àsìkò yìí gan-an, ìyẹn asiko ti konilegbele ń lọ káàkiri Nàìjíríà, pàápàá bí Ààrẹ Buhari tún ṣe sọ pé ó pọn dandan kí ilẹ̀kùn ipinlẹ Ogun, Eko ati Abuja wá ní ti tipa, àti pé ẹnikẹni kò gbọ́dọ̀ jáde síta. 

Ijọba Eko ati Abuja tẹle ọ̀rọ̀ Ààrẹ Buhari, bẹẹ naa ni Gomina Abiọdun náà tẹle àṣẹ Ààrẹ. 

Bí Ààrẹ Buhari ṣe pàṣẹ yìí lọsẹ mélòó kan sẹyin lo tí woye ìyá tí yóò jẹ àwọn aráàlú, pàápàá àwọn tó jẹ́ pé bí wọn kò bá jáde lojumọ, wọn kò lè rí owó jẹun depodepo wí pe wọn yóò bọ mọlẹbi wọn, ìdí re tó fi fi ọjọ́ márùn-ún kún tiẹ̀ fún àǹfààní àwọn tí kò ti í sì ni imurasilẹ. 

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọn ń gbé oṣuba káre fún Gomina Abiọdun, pàápàá bo tún ṣe sọ pé ààyè ṣí silẹ fáwọn èèyàn láti máa jáde laarin ọjọ́ méjì-méjì títí ọjọ́ mẹ́rìnlá yóò fi pe. 

Bí Ààrẹ tún ṣe báwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ laipẹ yìí, ìyẹn lọ́jọ́ tí ọjọ́ mẹ́rìnlá náà pé wí pé àfikún ọjọ́ mẹ́rìnlá mi-ín tún ti gùn ọjọ́ mẹ́rìnlá tó parí làwọn èèyàn tún ti bẹ̀rẹ̀ si í pariwo pé ìyá ńlá ni yóò jẹ fún wọn.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀, latari gbogbo àwọn esi tó tẹ Gomina lọ́wọ́ láàárín asiko konilegbele náà wí pé ebi ń pá àwọn èèyàn, ṣùgbọ́n àǹfààní tó fi silẹ jẹ́ kí ebi náà dinku. Èyí ló tún jẹ́ ki Gomina Abiọdun tún sọ pé ààyè náà ṣì ṣí silẹ, ṣùgbọ́n tó ṣeé ṣe káwọn yìí padà bí nnkan bá ṣe ń lọ.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI