ILEEṢẸ ỌLỌPAA IPINLẸ OGUN TU AṢIRI IKU TO PA GBAJUMỌ DPO, OLUṢẸGUN DADA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 6, 2020

ILEEṢẸ ỌLỌPAA IPINLẸ OGUN TU AṢIRI IKU TO PA GBAJUMỌ DPO, OLUṢẸGUN DADA

L’ọjọ Sande ana ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ Kọmiṣanna wọn, Kenneth Ebrimson ti gbe atẹjade sita, ninu eyi ti wọn ti tu aṣiri iku to pa ọkan lara awọn ọlọpaa n’ipinlẹ naa, iyẹn Ọgbẹni Oluṣẹgun Dada gto jẹ DPO Ibara nilu Abẹokuta.

Ọjọ Ẹti Fraide ọsẹ to kọja yii la gbọ pe Dada ku si ọsibitu FMC to wa ni Idi-Aba, Abẹokuta lẹyin aisan rampẹ, tiroyin naa si gba igboro kan.

Ko pẹ ti iroyin iku Dada jade sita l’awọn kan ti bẹrẹ si i gbe e kaakiri wi pe iku ọkunrin naa ko ṣẹyin Ara-ọrun, iyẹn Eegun ti wọn gba aṣọ lara rẹ lọjọ Ajẹ Mọnde ọsẹ to kọja lọ latari bo ṣe lugbadi ofin konilegbe ati jijina-sira-ẹni lasiko aarun Coronavirus yii.

Agbegbe Ijẹja la gbọ pe ọwọ ti tẹ Ara-ọrun naa, ti wọn si wọ lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Ibara, nibi ti Dada ti jẹ ọga. Ibẹ si la gbọ pe wọn ti gba aṣọ eegun lara rẹ, ko to o di pe wọn pada fi silẹ.

Eyi lo jẹ k’awọn ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa maa gbe e kaakiri wi pe Ara-ọrun naa lo da seria fun DPO naa, to si jẹ pe iku lo gbẹyin ẹ.

Bi iroyin naa ṣe jade sita, t’awọn eeyan si ti n gbagbọ ninu ẹ lo mu ki agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi gbe atẹjade sita, nibi to ti tu aṣiri iku ọkunrin naa sita wi pe o ti le l’oṣu mẹta ti Dada ti wa lori idubulẹ aisan, ti ko si lanfaani lati yọju si ọfiisi rẹ ko to o ku.

Oyeyẹmi sọ pe awọn alaimọkan lo n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa kaakiri, ati pe k’awọn araalu ma ṣe gba iroyin naa gbọ rara, nitori pe Ara-ọrun ti gba aṣọ lara rẹ tapa si ofin, o si ti bẹbẹ, ko da, o lọjọ naa ni wọn fi silẹ lai gba ohunkohun lọwọ rẹ.

Lara awọn to tun gbe iroyin iku to pa Dada fun si wa leti jẹ ko ye wa pe aisan to ṣeku pa Dada ti wa lara rẹ tipe, ati pe oṣu kinni ọdun yii laisan naa yiwọ, ti wọn fi bẹrẹ si i gbe e kaakiri ọsibitu.

Oṣu keji ọdun yii la gbọ pe ara Dada ya, to si pada sẹnu iṣẹ rẹ, ṣugbọn ko tun to bi ọsẹ meji ti wọn ni aisan naa tun yiwọ, ti wọn fi gbe e pada si ọsibitu FMC to wa ni Abẹokuta.

A gbọ pe aisan jẹjẹrẹ inu kidinrin lo n da Dada laamu, ti wọn si fẹẹ ṣiṣẹ abẹ fun un. Wọn ni lọjọ ti Dada dagbere faye yii gan an ni wọn fẹ ẹ ṣiṣẹ abẹ naa fun un, gbogbo eto ni wọn lo o ti pari lati ṣiṣẹ naa ko to o dakẹ.

Ibanujẹ nla n’iku Dada jẹ fun ọpọ eeyan tori pe ẹni t’awọn eeyan nifẹ si i daadaa ni, ti ki i si i ṣoju-ṣaaju rara.

A ti ẹ gbọ pe Dada n kọ ile kan lọwọ sagbegbe Adigbe nilu Abẹokuta, to si ti fẹ ẹ pari ile naa ki ọlọjọ to o de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI