MI O MỌ PE IBALOPỌ DÙN TO ÈYÍ, MI O ṢIṢẸ ỌLỌ́RUN MỌ - RẸFURẸNDI SISITA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 6, 2020

MI O MỌ PE IBALOPỌ DÙN TO ÈYÍ, MI O ṢIṢẸ ỌLỌ́RUN MỌ - RẸFURẸNDI SISITA PARIWO SITA


Ọrọ Yorùbá kan ló sọ pé 'bí ọmọ ologini bá ti tọ ẹ̀jẹ̀ wo, kò tún fẹnu kan ekolo mọ' wọ̀nyí gan án lọrọ tó lọ nibamu pẹ̀lú bí ọkàn lára àwọn sisita nílé ìjọsìn aguda, ìyẹn Kátólíìkì (Catholic) ṣe pariwo síta wí pé kò sẹni tó lè dá òun dúró láti lọ ọ ṣe ìgbéyàwó, nítorí tòun kò mọ pe inú ìgbèkùn lòun wá láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Obìnrin náà tó lo ó ti pẹ tòun ti ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ṣọọṣi Kátólíìkì náà sọ pé asiko re e tòun yóò jaye orí òun, tí kò sì sẹni tó lè dá òun dúró lailai. 

Orí ìkànnì ayélujára tí Instagram ni sisita yìí gbé ọ̀rọ̀ náà sì wí pé òun kò mọ pe ibalopọ dùn ju ẹ̀kọ́ tí wọn ń kọ wọn ní ṣọọṣi láti sìn Ọlọ́run, lai mọ pe irọ lásán ni ẹkọ náà jẹ. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, ọsẹ tó kọjá yìí ni Rẹfurẹndi sisita náà gbé ara rẹ silẹ fún ọrẹkùnrin rẹ láti ja ibale rẹ, bó ṣe ṣetán lo gba orí ìkànnì ayélujára rẹ lo, tó sì lọ ọ ṣàlàyé bo ṣé gbádùn ibalopọ náà tó, tó sì lòun kò ṣiṣẹ Ọlọ́run. 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ lo tí sọ pe "Mi ó mọ pe ṣe ni mo ń fi àkókò mi ṣòfò dànù láti jẹ onibale (virgin), mo ti ṣetan láti ṣe ìgbéyàwó. Àná ni mo padà tọ ibalopọ wo, mi ò sì ro pe mo lè fi silẹ mọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI