ỌNA TÁWỌN CHINA TÚN FẸ́ Ẹ GBA FÌYÀ JẸ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ RE E - NAFDAC PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 7, 2020

ỌNA TÁWỌN CHINA TÚN FẸ́ Ẹ GBA FÌYÀ JẸ ILẸ̀ ÁFRÍKÀ RE E - NAFDAC PARIWO SITA


Àjọ tó ń mojuto oúnjẹ àti oogun lorilẹ-ede Nàìjíríà, ìyẹn National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC) lọ́jọ́ Aje, Mọnde àná tí pariwo síta wí pé káwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ́ra fún oogun Chloroquine tí wọn fẹ ẹ kò wọlé sorilẹ-ede yìí. 

Nínú atẹjade tí ọga àgbà àjọ náà, Mojisọla Adeyẹye fi síta lo ti tú àṣírí yii wí pé  ayédèrú oogun chloroquine phosphate 250mg ni wọn ń pín káàkiri ilẹ̀ Áfríkà báyìí. 

Adeyẹye sọ pé àjò eleto ìlera agbaye, ìyẹn World Health Organisation (WHO) lo tá wọn lolobo wí pé oogun náà tí wọ orílẹ̀ -Èdè Cameroon, àwọn èèyàn nibẹ sì ti ń rí ipa rẹ wí pé ayédèrú ni. 

O ni ileeṣẹ kan tí wọn pé ní Jiangsu pharmaceutical Inc, Astral pharmaceutical New Bhupalpura to wa ni China lo ṣe oogun náà síta, láti fi ṣàkóbá fáwọn èèyàn.

Ninu atẹjade náà lo tí sọ pé oogun chloroquine lo jẹ́ pé kò làwọn èròjà tó lè ṣe agọ̀ ara nire bí í Active Pharmaceutical Ingredient (API), tí wọn sì ti ń kó o jáde lọpọ yanturu. 

“Lilo oogun chloroquine phosphate 250mg  ti ko kún ojú òṣùwọ̀n yìí lè yọrí sí àìsàn tí kò gboogun tàbí iku"

Bẹẹ lo ni ayédèrú ìwé àṣẹ tí NAFDAC ni wọn ń lo fi tà oogun náà, tó sì ni nọ́mbà tó wà lára oogun yìí ni 028060 ko lontẹ ìjọba nínú. 

O tún fi kún un pé yatọ si ti ileeṣẹ Jiangsu, ileeṣẹ mi-in náà, Astra pharmaceuticals, New Bhupalpura ni China náà ń ṣe tí wọn pẹlu ayédèrú nọ́mbà ontẹ tí wọn kọ sára àwọn oogun yìí ni 0587612, to sì ni kí gbogbo àwọn alagbata àti onibara oogun kiyesara oogun yìí, kí wọn sì má gba a láàyè láti wọ Nàìjíríà. 

O wa rọ àwọn èèyàn pé bí wọn ba ti kofiri àwọn oogun yìí, kí wọn tètè fi tó ileeṣẹ NAFDAC létí nípa pípé nọ́mbà 0800-1-NAFDAC ati 0800-1-623322.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI