O TÁN O! ỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ NAIRA MARLEY O, BẸ́Ẹ̀ NI WỌN ṢÍ Ń WÁ ẸNIỌLA BADMUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 7, 2020

O TÁN O! ỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ NAIRA MARLEY O, BẸ́Ẹ̀ NI WỌN ṢÍ Ń WÁ ẸNIỌLA BADMUS


Ileeṣẹ ọlọpaa ìpínlẹ̀ Eko ti fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé gbajumọ olorin nnì, AbdulAzeez Faṣọla, ẹni tí pupọ àwọn èèyàn mọ sì Naira Marley tí wa lahamọ àwọn.

Opin ọ̀sẹ̀ tó kọjá ní Funkẹ Akindele, ìyẹn Jẹnifa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí fún ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello, to sì pe ọpọ èèyàn lagboole amuludun láti bá a ṣajọyọ. 

Ana ni ile ẹjọ́ Majisireeti tó wà ní Ọgbà, Eko ju Funkẹ àti ọkọ rẹ sì ahamọ ọlọjọ mẹ́rinla gbáko, tí wọn yóò sì ṣiṣẹ sìn ìjọba pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbà táwọn méjèèjì yóò san gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn. 

Naira Marley ni ọga ọlọpaa ìpínlẹ̀ Eko, Hakeem Odumosu fi ye wá pé yóò fojú bale ẹjọ́, tòun náà yóò sì gba ìdájọ́ rẹ bo ti tọ, àti bó ti yẹ. 

Bẹẹ ni wọn jẹ kò ye wá pé àwọn sí ń wá àwọn yòókù tó na pápá bora, lára wọn ni Ẹniọla Badmus wá, tó sì ni ẹlẹṣẹ kan kò ní í lọ lai jìyà. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI