ACTOR, OLÓRÍ ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN N'IKORODU TÍ HA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 4, 2020

ACTOR, OLÓRÍ ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN N'IKORODU TÍ HA O


Láti bí oṣù mélòó kan sẹ́yìn báyìí là gbọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tí ń kó àwọn aráàlú kọ̀kan sókè, tí wọn kò sì jẹ ki wọn sún oòrùn asundọkan. 

Inú ibẹrubojo làwọn ara ilu Ikorodu wá látìgbà tí konilegbele tí bẹ̀rẹ̀, nítorí wàhálà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí tó ń fojoojumọ yọ wọn lẹ́nu. 

Bí ìròyìn náà ṣe tẹ ọga ọlọ́pàá Zone, Ahmed Iliyasu lọ́wọ́ lo tí pàṣẹ wí pé àwọn èèyàn náà gbọ́dọ̀ de ọdọ òun, nítorí tòun fẹ ẹ fojú kan wọn.

Iṣẹ ofintoto táwọn ọlọ́pàá ṣe ló jẹ́ kí àṣírí Mukaila tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ Actor tu sì wọn lọ́wọ́. 

Àwọn àgbègbè bí í Maya, Itele, Igode àti Adamọ n'ilu Ikorodu, ipinlẹ Ekoo ni Actor ń dá láàmú. 

Bí ọwọ ṣe tẹ Mukaila lo tí sáré mú àwọn ọlọ́pàá lọ sílè rẹ láti yẹ ẹ wo, nibẹ sì ni wọn ti bá ìbọn, ọta ìbọn marundinlọgọta, àáké, oogun abẹnugọngọ àtàwọn nnkan miin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI