ÌJỌBA KWARA YAN IGBIMỌ COVID-19 NÍ WỌỌDU ALANAMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 5, 2020

ÌJỌBA KWARA YAN IGBIMỌ COVID-19 NÍ WỌỌDU ALANAMU


Láti tún lè jẹ ki awọn aráàlú jẹ ìgbádùn mudun-mudun ìjọba awaarawa, ọ́jọ́ Ajé, Mọnde àná n'ijọba ipinlẹ Kwara tún gbé igbimọ Covid-19 ńlá kan dìde ní wọọdu àárín-gbùngbùn Alanamu tó wà n'ijọba ìbílẹ̀ Ilorin West, ipinlẹ Kwara. 

Igbimọ náà n'ijọba gbé dìde láti ṣabojuto ọ̀nà láti dẹ́kun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19, ìyẹn koronafairọọsi to ń dá gbogbo àgbáyé láàmú. 

Nígbà tó ń gbé ọ̀pá àṣẹ lè wọn lọ́wọ́, Kọmiṣanna feto ìlera n'ipinlẹ náà, Dọkita Raji Razaq gba àwọn igbimọ náà lamọran láti kọjú mọ ìṣẹ t'ijọba gbé lé wọn lọ́wọ́. 

Nibẹ náà lo tún ti gbé oṣuba káre fáwọn èèyàn tó wà ní wọọdu náà lórí àwọn ọ̀nà tí wọn tí ń gba láti dẹ́kun bí aarun Covid-19 ṣe ń tàn káàkiri.

Dọkita Razaq to ṣojú akọwe àgbà l'ẹka eto ìlera, Dọkita Abubakar Ayinla lòun mọ rírí ipa tí wọọdu náà ń kọ lásìkò yìí, ìdí re e tó ní ìjọba tètè dìde láti sì wọn. 

Igbimọ náà ni Kọmureedi Yẹkin AbdulKareem Agunbiade jẹ́ alaga rẹ. Lára àwọn ọmọ igbimọ náà ni: Abdul Ganiyu Jaja, Muyideen Ikọlaba, Rabiu Suleiman, Isiaka Issa, Woli Ọnagun, Captain Isiaka, Nurudeen Jaji. 

Àwọn mi-in ni: Yinka Babatunde, Razaq, Adio, Saliu Otubu, Alaaji M Kobe, Rasheedat Okolona, Ibraheem Y Wood, Ọjọgbọn Ajibọla Akanbi, Alabi Onimago, Ṣarafa Onituwo, Rabiu Suleiman ati Suleiman Yahaya. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI