ỌPẸ O! ORÍ KO GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ YỌ LỌ́WỌ́ IKÚ ÒJIJÌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 4, 2020

ỌPẸ O! ORÍ KO GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ YỌ LỌ́WỌ́ IKÚ ÒJIJÌ


Kani kí i ṣe pé Ọlọ́run dúró tì gbajugbaja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nnì, Kọlawọle Atanda Adejojo tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ sì Kasnaty dáadáa ní, bóyá ohun tá ń kọ yìí kọ lao bá máa kọ.

Odu ni Kasnaty, kí í ṣaimọ f'oloko nìdí iṣẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí rédíò àti tẹlifiṣan lorilẹ-ede Nàìjíríà, pàápàá n'ipinlẹ Ogun.

Látìgbà tí eto konilegbele láti dẹkun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19 ni Kasnaty tí ń lọ káàkiri láti máa mọ nnkan tó ń ṣẹlẹ̀ s'awọn aráàlú, pàápàá láti mọ báwọn èèyàn ṣe ń tẹle àwọn òfin àti ìlànà ìjọba. 

Kí i ṣe ahesọ tàbí asọdun wí pé gbogbo àgbègbè tó wà n'ipinlẹ Ogun ni Kasnaty tí de látìgbà tí konilegbele yìí tí bẹ̀rẹ̀. Bó sì ṣe ń lọ káàkiri lo ń pàdé oríṣiríṣi àwọn èèyàn ti wọn n sọ nnkan ti ojú wọn ń rí.

Báwọn kan ṣe ń bẹbẹ fún iranlọwọ, bẹ́ẹ̀ làwọn kan ń gba ìjọba lamọran. Èyí tó lékè gbogbo rẹ ni bo ṣe jẹ́ pé kolonka làwọn tí wọn tí jẹ àǹfààní ńlá lára Kasnaty bo ṣe ń lọ káàkiri yìí, lára wọn sì ni ti Ìya Saheed Onirọba. 

AWÍKONKO gbọ pé ìwúrí ńlá lo jẹ́ fún ìjọba ipinlẹ Ogun nígbà tí wọn gburo àwọn ipa tí Kasnaty nko nípa bó ṣe ń lọ káàkiri, táwọn èèyàn sì tún gbé oṣuba káre fún wọn pẹ̀lú oúnjẹ àti owó tí wọn rí gbà. 

Èyí ni wọn lo ó mú kijọba Dapọ Abiọdun ṣèlérí láti fún Kasnaty làwọn ẹbun tó jọju dáadáa, pàápàá lórí tí ìpolongo tó tún ṣe lórúkọ ìjọba. 

O ṣeni láàánú wí pé títí di àsìkò tá a kọ ìròyìn yìí tán, ìlérí ahọ́n lásán ni ìjọba ṣe gẹ́gẹ́ bá a ṣe gbọ.

AWÍKONKO gbọ pé lànà tí í ṣe ọjọ́ Àìkú, ìyẹn Sannde ni Kasnaty tún lọ bo se maa n lọ, agbegbe kan tí wọn ń pè ní Ọbantoko ni ọkùnrin ọmọ bibi ipinlẹ Ọṣun náà lọ gẹ́gẹ́ bí ìṣe ẹ.

Ara ilu Kanada kan ni Kasnaty ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọn ní ṣe ló déédéé ṣubú lulẹ, ó táwọn tó wà nibẹ sì sáré gbé e lọ sí ọsibitu kan tó wà nítòsí, níbi tó ti gba ìtọ́jú díẹ̀.

Fún bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí là gbọ pé Kasnaty too làjú ni ọsibitu náà lẹ́yìn àdúrà agbayipo táwọn amugbalẹgbẹ rẹ ń gba fún un. 


Àwọn olólùfẹ́ Kasnaty lórí fesibuuku tí wọn rí nnkan tó ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Kasnaty ń ṣe fọ́nrán lọ́wọ́ ni wọn ń gbàdúrà kíkankíkan fun-un. 

Ohun táwọn tó rí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń sọ ní pe ìṣẹ̀lẹ̀ náà kii ṣojú lásán, táwọn kan sì ń sọ pé o ṣeé ṣe kó jẹ ọfa ni, ṣùgbọ́n táwọn olólùfẹ́ rẹ tí bẹ̀rẹ̀ aawẹ àti àdúrà báyìí. 

Ìbéèrè táwọn èèyàn ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn báyìí ni pé ṣe Kasnaty yóò tẹsiwaju àwọn àkànṣe eto orí fesibuuku yìí ni ọlá pẹ̀lú bo ṣe jẹ́ pé gbogbo asiko táwọn èèyàn bá wà nílè lo máa ń lọ káàkiri.

AWÍKONKO gbìyànjú láti bá ọkùnrin náà sọ̀rọ̀ láti béèrè àlàáfíà rẹ, ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú wí pé aago rẹ kò lọ tá a fi kọ ìròyìn yìí tán. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI