AYẸYẸ ỌDÚN KAN! VGN ÌPÍNLẸ̀ OGUN GBÉ OṢUBA RABANDẸ FÚN GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 29, 2020

AYẸYẸ ỌDÚN KAN! VGN ÌPÍNLẸ̀ OGUN GBÉ OṢUBA RABANDẸ FÚN GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN


Ileeṣẹ eleto ààbò Fijilante lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹ̀ka t'ipinlẹ Ogun lábẹ́ Kọmanda Ọlanrewaju Nureni Adedoyin tí gbé oṣuba rabandẹ-rabandẹ fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, Ọmọba Dapọ Abiọdun lórí akitiyan rẹ nípa eto ààbò.

Kọmanda Adedoyin lo gbé oṣuba káre fún Gómìnà Abiọdun nínú atẹjade tó kọ láti fi kí Gómìnà fún tí ayẹyẹ ọdún kan tó dé orí ipò, pàápàá fún tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún láyé.

O ni ipa tí Gómìnà Abiọdun tí kò lẹka eto ààbò láàárín ọdún kan kò ṣeé fọwọ́ rọ tí sẹ́yìn, tó sì ṣàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà Ojulalakanfinṣọri. 

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Àwa kò lè ṣai gbé oṣuba rabandẹ fún Gómìnà wá, Gómìnà aráàlú tó mú iṣẹ eto ààbò lokunkundun, to sì ń ṣiṣẹ́ ojulalakanfinṣọri loore-koore. Lára àwọn nǹkan tí kìí jẹ́ kí ìlú dagbasoke ni ọrọ ẹlẹyamẹya, eyi ti Gómìnà Abiọdun kò faaye gba ninu ìjọba rẹ.

"Pẹlu ìdùnnú àti ayọ̀ là fi ń dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọmọba Dapọ Abiọdun lórí iṣẹ takuntakun tó ń ṣe káàkiri origun mẹ́rin ipinlẹ yìí. Àwọn ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú tijọba yìí tí ṣe jẹ́ koriwu fáwọn aráàlú, táwọn èèyàn sì ń dúpẹ́ pé Olùgbàlà wọn tí de. 

"Irú oore-ọ̀fẹ́ báyìí kò wọpọ láti máa ṣe ayẹyẹ ọgọ́ta ọdún nínú àṣeyọrí tó lọọrin bíi ti Gómìnà aráàlú. Ìgbà yín ń tú wá lára, pàápàá nileeṣẹ VGN. A sì ń fi asiko yii dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àlàáfíà tí ẹ ń jẹ kò jọba láàárín àwa eleto ààbò nipinlẹ Ogun."

Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin gbàdúrà fún ẹmi gígùn nínú ayọ, àlàáfíà àti ifọkanbalẹ fún Gómìnà Abiọdun. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI