AYẸYẸ ỌDÚN KAN! ILEEṢẸ ELETO ÀÀBÒ SO-SAFE GBÉ OṢUBA KARE FÚN GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 29, 2020

AYẸYẸ ỌDÚN KAN! ILEEṢẸ ELETO ÀÀBÒ SO-SAFE GBÉ OṢUBA KARE FÚN GÓMÌNÀ DAPỌ ABIỌDUN


"Ohun ayọ̀ lo jẹ́ láti ni Gómìnà tó fẹ́ràn eto ààbò báyìí, ẹni tí ìjọba rẹ dúró lórí òtítọ́ àti ìgbàgbọ́ wí pé ẹ̀mí àti dúkìá aráàlú nìkan ló lè mú kí àlàáfíà, ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan fẹsẹmulẹ, tí yóò sì tún mú kí eto ọ̀rọ̀ ajé tẹsiwaju."

Won yìí ni ọ̀rọ̀ ìkíni tí Kọmanda Olusọji Ganzallo to jẹ́ olùdarí ileeṣẹ eleto ààbò So-Safe Corps nipinlẹ Ogun fi kí Gómìnà Dapọ Abiọdun laarọ òní to jẹ́ ayajọ ọdún kan tó gbà ọpa àṣẹ gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà, àti ayẹyẹ ọgọ́ta ọdún loke-eepẹ. Agbẹnusọ ileeṣẹ náà, Ọgbẹni Moruf Yusuf lo fi síta.

"Ko si iye méjì kan wí pé ipilẹ tó dúró digbi tí àwọn àfojúsùn tí ìjọba yìí fara ti ní 'eto ààbò fún gbogbo eeyan' lai fi ọ̀rọ̀ ẹlẹyamẹya tàbí ojúsàájú tàbí ọrọ òṣèlú ṣe. Fún èyí, gbogbo ojú ni yóò rẹrin nígbà tí ọkàn wọn ba n kún fún ayọ." 


O ni ileeṣẹ So-Safe Corps jẹ ọkan lára àwọn ẹlẹ́rìí tó jẹ́ àǹfààní ìjọba yìí, tó sì ni ìjọba yìí tí ń sọ ọpọ àwọn ẹ̀ka ileeṣẹ àti àwọn àkànṣe iṣẹ tó ti di òkú jí. 


Ganzallo tún jẹ́ kó di mimọ pé iṣẹ àwọn tún ti yatọ si tẹ́lẹ̀, pàápàá látìgbà táwọn tí gba àwọn irinṣẹ amuṣẹya bíi mọto àti ọkada agberapa {Motorbikes} tuntun lọ́wọ́ ìjọba.

"Ọlọ́run yóò bukun fún ọjọ́ orí yín tuntun àti ìjọba yín bí ẹ ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún kan ni ọfiisi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI