ÌDÀÀMÚ ŃLÁ TÚN DE BA SANWÓ-OLÚ NÍTORÍ ÌDAṢẸ́SÍLẸ̀ ÀWỌN DỌKITA L'ÉKÒÓ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 21, 2020

ÌDÀÀMÚ ŃLÁ TÚN DE BA SANWÓ-OLÚ NÍTORÍ ÌDAṢẸ́SÍLẸ̀ ÀWỌN DỌKITA L'ÉKÒÓ


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú ìdààmú àti iporuru ọkàn ni Gomina ipinlẹ Èkó, Babajide Sanwo-Olu wá báyìí, tó sì ń bẹbẹ wí pé káwọn dọkita má ṣe bí agbára wọn ṣe tó.

L'ọ́jọ́ Wẹside àná ni ẹgbẹ́ àwọn eleto ìlera lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Nigerian Medical Association, NMA, ẹ̀ka t'ipinlẹ Èkó pàṣẹ wí pé kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera jókòó sílè fún ìgbà díẹ̀ tí wọn kò tíì mọ, títí tí wọn yóò fi yanjú àwọn wàhálà tó ń koju wọn lọdọ àwọn ọlọ́pàá. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní ṣe làwọn ọlọ́pàá ipinlẹ Èkó dá àwọn dọkita láàmú, pàápàá àwọn tó ń ṣe ìtọ́jú àwọn tó ń ní àrùn Covid-19, ìyẹn Koronafairọọsi. 

AWIKONKO gbọ́ pé ọpọ ìgbà táwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera bá ń kọjá lọ làwọn ọlọ́pàá máa ń dá wọn lọ́nà, tí wọn yóò sì dá wọn padà síbi tí wọn tí ń bọ̀, èyí tí wọn loo tako àṣẹ tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ lórí itankalẹ àrùn Koronafairọọsi. 

Nínú atẹjade alaga ẹgbẹ́ náà, Dọkita Saliu Oseni fi síta fáwọn òṣìṣẹ́ ìlera pátápátá nipinlẹ Èkó lo tí sọ pé gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ wọn gbọ́dọ̀ padà sílè laago mẹ́fà irọlẹ, àti pé wọn kò gbọdọ padà sí ẹnu iṣẹ wọn dìgbà tí wọn yóò fi pe wọn padà. 

Ó làwọn kò lè là ojú silẹ káwọn ọlọ́pàá máa fìyà jẹ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn lọ́nà aitọ, àti pé àwọn kò lè gbà kí wọn máa ṣíṣẹ lai si eto ààbò tó péye fún wọn. 

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, Kọmiṣanna f'eto ìròyìn, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ sọ pé àwọn tí yanjú ọ̀rọ̀ náà, àti pé kò sí nnkan tó jọ pé àwọn eleto ìlera ń dá iṣẹ silẹ mọ. 

Ó ní kété tí ìròyìn náà tí tẹ àwọn lọ́wọ́ làwọn tí gbé igbesẹ láti yanjú ẹ, táwọn sì ti báwọn ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ẹ, àti pé àwọn náà tí ṣetan láti tẹ́lẹ̀ òfin àti ìlànà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI