Ẹ GBỌ NNKAN TÍ AMOSUN, DAPỌ ABIỌDUN SỌ L'ORI IKÚ IMAAMU ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 26, 2020

Ẹ GBỌ NNKAN TÍ AMOSUN, DAPỌ ABIỌDUN SỌ L'ORI IKÚ IMAAMU ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ


Kii ṣe ìròyìn tuntun mọ wí pé Imaamu àgbà ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Oloye Sheik Ayinde Liadi Ọrunṣolu tí jáde láyé lẹni ọdún mejidinlọgọrun-un {98}, tí àwọn èèyàn sì ti bẹ̀rẹ̀ sii fi ọ̀rọ̀ ibanikẹdun ranṣẹ sáwọn ẹbí olóògbé loriṣiriṣi. 

Ní kété tí ìròyìn náà tẹ Gómìnà àná nipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun lọ́wọ́ lo tí sáré tẹkọ̀ létí lọ sílè Olóògbé náà tó wà ní Ìsàlẹ̀-Igbein n'ilu Abẹ́òkúta láti báwọn mọlẹbi rẹ kẹ́dùn.

Lára àwọn tó kọwọrin pẹ̀lú Sẹnetọ Amosun ni Minisita tẹ́lẹ̀ri f'ọrọ ohun èlò àlùmọ́ọ́nì ni Nàìjíríà, Ọnọrebu Ṣarafa Tunji Iṣọla, Ọnọrebu Idowu Olowofuja tòun náà jẹ ọkan lára àwọn ọmọ ilé igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun tẹ́lẹ̀ àtàwọn mi in. 


Nnkan bí aago mẹjọ aabọ aarọ òní là gbọ pé wọn délé Olóògbé náà láti báwọn èèyàn kẹdun.

Amosun nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ibanikẹdun, ó ní àdánù ńlá ni ikú Oloye Ọrunṣolu jẹ fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà, pàápàá àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò. 

Bẹẹ lo gbàdúrà fún gbogbo ẹbí lórí àdánù náà. 

Bákan náà, Gómìnà ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun fi ọ̀rọ̀ ibanikẹdun ranṣẹ sáwọn mọlẹbi olóògbé, ati gbogbo ọmọ Ẹ̀gbá lapapọ. 

Abiọdun ni òun kò lè gbàgbé ipa tí Imaamu agba náà kò nipinlẹ Ogun láti jẹ ki àlàáfíà jọba, àti pàápàá tó tún ń kọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Isilaamu lọ́nà tó ye kooro. 

Ó ní fún gbogbo ọjọ́ ayé Baba náà lo fi ń gbàdúrà, tó sì jẹ́ pé àwọn àdúrà rẹ ń ṣiṣẹ takuntakun fáwọn èèyàn.

Ọdún 2003 ni Olóògbé Ọrunṣolu di Imaamu àgbà ilẹ̀ Ẹ̀gbá, to sì jẹ pe látìgbà náà lo tí ń fi àlàáfíà bá gbogbo èèyàn ló kọ too dagbere fáyé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI