ELEGUṢI JÁDE LÁYÉ LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 26, 2020

ELEGUṢI JÁDE LÁYÉ LOJIJI


Alawe tilu Ikate nipinlẹ Èkó, Olóyè Murtala Adedoyin Eleguṣi tí jáde láyé lẹni ọdún mẹrinlelaadọrin {74}.

Ohun taa gbọ ni pé ojú ọrùn ni Olóyè Eleguṣi gba sọdá s'ọrun alakeji laarọ òní, ọjọ́ Iṣẹgun, ìyẹn Tuside. 

Àwọn mọlẹbi Eleguṣi nínú atẹjade tí wọn fi síta laarọ òní ni wọn ti jẹ́ kó di mimọ. 

Nígbà tí wón ń ṣàpèjúwe Olóògbé náà, wọn ní àdánù ńlá lo jẹ́ fáwọn nítorí pé ọkàn lára àwọn tó mọ ìtàn ìlú Ikate-Eleguṣi, Eti-Ọsa dáadáa ní Olóògbé náà jẹ. 

Wọn ní Baba náà tí báwọn ja láti bá wọn parí aawọ tó wáyé nípasẹ̀ ìtàn òtítọ́ nípa ìlú náà èyí tó ti fòpin sí ọpọ wàhálà. 

Àwọn ìyàwó, àwọn ọmọ àtàwọn ọmọ-ọmọ ni wọn loo gbẹyin Baba náà. Kí Ọlọ́run tẹ ẹ sì afẹ́fẹ́ rere. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI