Ẹ WO OJU SPARTAN TO N P'AWỌN EEYAN DANU L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 4, 2020

Ẹ WO OJU SPARTAN TO N P'AWỌN EEYAN DANU L'OGUN


T'ọsan-t'oru ni gbogbo ileeṣẹ eleto ààbò pátápátá n'ipinlẹ Ogun fi ń wá ọdọmọkunrin tí ẹ ń wo àwòrán rẹ yìí, Feyiṣọla Spartan-Freeman làwọn èèyàn tún mọ sì í. 

Láti ọdún tó kọjá là gbọ pé Spartan tí ń ṣe àwọn ará Ogere, Ipẹru, Ikẹnnẹ ṣìbáṣìbo, tí wọn sì ti lọọ f'ọrọ rẹ tó àwọn ọlọ́pàá létí. 

Oṣù Kínní ọdún yìí ni wọn ní Spartan bẹ̀rẹ̀ si í fipá báwọn obìnrin laṣepọ, tó sì tún máa ń báwọn èèyàn ja lai nídìí. 

AWÍKONKO gbọ pé ilé ẹ̀kọ́ gbogboniṣe tí Mọshood Abiọla tó wà nílùú Abẹ́òkúta tí kẹ́kọ̀ọ́ jáde, ilé-ẹ̀kọ́ náà là gbọ pé ó ti bẹ̀rẹ̀ si í báwọn ọmọ ẹlẹgbẹ òkùnkùn rin

Àwọn sí ní wọn kọ ọ bí wọn ṣe ń mú ọtí, igbó àti sìgá. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì là gbọ pé ó dá orí rẹ ru tó fi ń ṣiwa hu sáwọn èèyàn. 

Laarin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí, kò dín ni èèyàn mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn ní Spartan tí pá dànù, tí mẹta nínú àwọn tó pa dànù yìí sí jẹ ọlọdẹ. 

Ní báyìí, gbogbo aráàlú náà là gbọ pé wọn ń wá láti rí í mú, kí wọn lé fi jofin. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI