WAHALA ẸGBẸ OṢELU PDP TUN GBA ỌNA MI-IN YỌ L'EKITI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 4, 2020

WAHALA ẸGBẸ OṢELU PDP TUN GBA ỌNA MI-IN YỌ L'EKITI

Pẹlu wàhálà tuntun tó tún dìde nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Ekiti báyìí, afaimọ kò má jẹ pe ọ̀nà láti tún pàdánù kọjá sísọ nínú ìdìbò ọdún 2023 ni wọn rawọ lè. 

Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà tí bẹ̀rẹ̀ si í tutọ síra wọn lójú káàkiri ipinlẹ náà báyìí, tí wọn sì ń leri síra wọn gidigidi.

Ki í ṣe ahesọ wí pé igun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lo wá nínú ẹgbẹ́ náà n'ipinlẹ Ekiti. Báwọn kan ṣe tẹle igun Gómìnà àná n'ipinlẹ náà, Ayọdele Fayọṣe, bẹ́ẹ̀ làwọn kan tẹle igun Sẹnetọ Abiọdun Olujimi.

L'Ọjọbọ, Tọside ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí làwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà yàn àwọn Olóyè wọọdu. 

Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ Fraide ni PDP tí igun Fayọṣe sọ̀rọ̀ síta wí pé ayédèrú igbimọ làwọn tí Olujimi yàn, nítorí pé kò ṣeni tó mọ wọn, àti pé ọjọ́ Tọside náà ni ìṣàkóso igun tí Fayọṣe dópin, nítorí náà ni wọn ṣe gbọ́dọ̀ fáwọn láàyè.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, agbẹnusọ Ayọdele Fayọṣe lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn, Ọgbẹni Lérè Ọlayinka sọ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà ni wọọdu marunlelaadoje {155} nínú mẹtadinlọgọsan {177} ni wọn ti dibo yàn, tí ìṣàkóso ọdún mẹ́rin wọn sì ti bẹ̀rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin ẹgbẹ́.

Ọlayinka sọ pé níbi tí àwọn olóyè táwọn yàn náà fi ẹsẹ mulẹ de, ó ní Amofin àgbà tó gbajumọ dáadáa, Amofin Niyi Idowu lo búra fún wọn.

Ninu ọrọ tiẹ̀ náà, alaga PDP Repositioning Movement l'Ekiti, Alaba Agboọla sọ pé Idowu kí í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ wọn, nítorí náà ni kò ṣe láṣẹ láti búra fún ẹnikẹ́ni. 

Agboọla sọ pé àwọn dúró lórí igbimọ tí alaga ẹgbẹ́ náà, Oloye Gboyega Oguntuwaṣe yàn, nítorí náà lo ṣe jẹ́ pé òfo lásán ni igbimọ táwọn igun kejì yàn, tí kò sì lẹsẹ nilẹ rárá. 

Bákan náà lo tún sọ pé ojúlówó àwọn olóyè ni wọn yàn lọ́jọ́ Fraide, tí wọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ láti ọjọ́ kinni oṣù karùn-ún tí a wà yìí, táwọn yóò sì gbé orúkọ wọn jáde laipẹ. 

Ohun tí àwọn èèyàn ń sọ bayii ni pé afaimọ kò má jẹ pe ilé ẹjọ́ làwọn èèyàn náà yóò padà yọrí sí, tó sì ṣeé ṣe kí wọn fà ọ̀rọ̀ náà títí d'asiko idibo ọdún 2023.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI