ÌJỌBA ALÁRAGBÀYÍDÁ! KWARA BẸ̀RẸ̀ ÀTÚNṢE ỌSIBITU OJÚ-ẸKÙN LỌ́NÀ ÌGBÀLÓDÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 26, 2020

ÌJỌBA ALÁRAGBÀYÍDÁ! KWARA BẸ̀RẸ̀ ÀTÚNṢE ỌSIBITU OJÚ-ẸKÙN LỌ́NÀ ÌGBÀLÓDÉ


Lọ́jọ́ Ajé, Mọnde àná ni ileeṣẹ to ń rí sì eto ìlera nipinlẹ Kwara {Ministry of Health} lewaju àwọn kọntiratọ láti ṣe àtúnṣe ọsibitu Ojú-Ẹkùn, ìyẹn Oju-Ekun Basic Health Centre tí wọn tí pá tí láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn.

Kọmiṣanna feto Ìlera nipinlẹ náà, Dọkita Raji Razaq lo lewaju ikọ náà lọ síbẹ̀, láti lè ṣe àtúnṣe ọsibitu yìí lọ́nà tí yóò bá ti ìgbàlódé mú. 


Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn loo tí pẹ tí wọ́n ti pá ọsibitu yìí tì nígbà táwọn èèyàn kò yà ibẹ̀ mọ. Wọn ní yatọ si pe àwọn akọṣẹmọṣẹ oniṣẹgun oyinbo tó jẹ́ tijọba wá lọsibitu yìí, síbẹ̀, àwọn ìjọba tó kọjá lọ kò yà sí idagbasoke rẹ. 

Kò sẹni to wọ ọsibitu náà tí kò níí bù sẹkun lori ipò táwọn ọsibitu káàkiri Ìpínlẹ̀ náà wá, èyí tó jìnnà sí tigba 1830s.


Kii ṣe asọdun tàbí ahesọ wí pé Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe gbogbo àwọn ọsibitu káàkiri ipinlẹ náà, tó fi mọ àtúnṣe àwọn ilé ẹ̀kọ́ pátápátá. 

Inú ìdùnnú àti ayọ̀ làwọn ọmọ ipinlẹ náà wá báyìí, lórí àwọn igbesẹ Gomina alaragbayida, AbdulRahman AbdulRazaq fún àwọn iṣẹ́ iwuri tó ti ṣe láàárín ọdún kan tó gbà ọ̀pá àṣẹ.

Àwọn agbaṣẹṣe náà tí ṣèlérí wí pé àwọn kò ní pẹẹ parí àtúnṣe náà. No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI