Ko sẹni tó gbọ sì ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí kò ṣe ní kayeefi, lórí bí gendekunrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Chima ṣe dáná sún ẹ̀gbọ́n rẹ, Victoria toyun-toyun.
Àdúgbò kan tí wọn pé ní TI C.A.C bus-stop lágbègbè Okokomaiko, ìjọba ìbílẹ̀ Ojo, Èkó ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù yìí.
Ọ̀rọ̀ oyún oṣù méjì tí wọn ni Victoria ni là gbọ pé ó dá wàhálà sílẹ̀ láàárín Victoria àti Màmá wọn tó ń tà oúnjẹ.
Lára àwọn ìròyìn taa gbọ ni pé Victoria gba mama rẹ létí níbi tó ń tà oúnjẹ nínú ṣọọbu, èyí ni wọn ní Chima gbọ tó fi sáré debẹ láti mọ nnkan tó ń ṣẹlẹ̀.
Wọn ní bo ṣe gbọ pé Victoria gba mama wọn létí lo muu gbé kẹẹgi kan tí wọn gbé silẹ, èyí tí wọn ní epo bẹntiroolu lọ wà nínú ẹ, tó sì fi gba Victoria, ẹ̀gbọ́n rẹ lórí.
Epo bẹntiroolu tó wà nínú kẹẹgi yìí ló yí dá lé Victoria lori, to sì gbaná lójijì.
Ariwo tí wọn ní Victoria ń pá lo mú káwọn tó wà nítòsí sáré debẹ láti pá iná ara rẹ, tí wọn sì gbé e lọ sí ọsibitu kan tó wà nítòsí, níbi tí wọn tí padà gbé e lọ sí ọsibitu jẹnẹra tí Alimọṣọ, èyí tó wà ní Igando.
Nibẹ sì ni wọn ti jẹ́ kó ye wọn pé òkú ní wọn gbé wa fún wọn, èyí ló mú kí wọn gbé e padà sílè.
Bí Chima ṣe rí nnkan tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kó bá ẹsẹ rẹ sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n tí wọn padà ríi mú níbi tó salọ.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá nípìnlẹ̀ Eko Bala Elikana ṣàlàyé pé lóòótọ́ ni pé ẹ̀gbọ́n ọmọbìnrin náà ló dáná sun-ún.
Bala fi kún un pé ẹjọ́ náà ti wà níwájú ẹ̀ka tó n rí sí ìwà ọ̀daràn ni Panti Yaba fún ìwádìí tó péye lórí ọ̀rọ̀ náà tí yóò sì fojú balé ẹjọ́ ní kòpẹ́kòpẹ́.
"Aburo rẹ̀ ló dáná sun-ún, o ni ẹ̀gbọ́n òun kò bọ̀wọ̀ fún ìyá àwọn tó, nítorí rẹ̀ sì ni oun ṣe dáná sun-ún láti bá a wí.
"Ìyá wọ́n naa farapa lásìkò tó n gbìyànjú láti paná lára ọmọ.
"A o gbé ọ̀daràn naa lọ ilé ejọ́ ni kété tí a ba ti parí ìwádìí tiwa nítorí àti gbà a kúrò lọ́wọ́ àgọ́ ọlọ́pàá okokomaiko, lọ sí Panti ni Yaba, yóò sì fojú balé ẹjọ́."
No comments:
Post a Comment