Àwọn gómínà ìpínlẹ̀ kan ti fí ẹdùn ọkàn wọn hà lórí bí àwọn
àwọn ọlọkọ̀ èrò ṣe kọti ògbọin sófin to dé ìrìnàjò láti ìpínlẹ̀ kan si òmíràn
lórílẹ̀-èdè Naijiria nítorí ààrùn coronavirus.
Ọ̀pọ̀ àwọn gómínà náà lóní ẹ̀rù ń bàwọn nítorí wọ́n le maa
pín àrùn náà káàkiri tí ààrùn náà yóò sì maa pọ̀ sii.
Níbáyìí ènìyàn to lé ni ẹgbẹ̀run ḿẹ́sàn ló ti ní ààrùn náà ti
ènìyàn to dín díẹ̀ ni ọ̀ọ́dúrún sì ti kú
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu, Nyesome Wike ti ìpínlẹ̀
Rivers, Godwin Obaseki ti Edo àti Kayode Fayemi Ekiti náà wà lára àwọn gómína
tó nàka àlébù sí àwọn ọlọ́pàá nítorí àwọn ló n gbàbọ̀de fáwọn ìpínlẹ̀.
Bákan náà ní ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe lórí Covid-19 tí ààrẹ Buhari
yàn tí bẹ̀nú àtẹ́ lu àjọ ọlọpàá lórí ọ̀nà tí wọ́n ǹ gbà mú ọ̀rọ̀ ìrìnàjò láti
ìpínlẹ kan sí òmíràn.
BBC
No comments:
Post a Comment