KI LẸ MỌ NIPA JẸSU OYINGBO? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 31, 2020

KI LẸ MỌ NIPA JẸSU OYINGBO?


Bi aye ba n yi, a maa ba aye yii ni nitori ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ, a ko si ri iru eyi ri, a fi n da ẹru ba ọlọrọ ni.

Oniruuru ilana ẹsin ati ijọ lo ti wa kaakiri laye atijọ, ti ihuwasi ati isesi wọn si jẹ manigbagbe, eyi ti ijọ Jesu Oyingbo jẹ ọkan ninu wọn.

Gẹgẹ bi a ti kaa ni oju opo Wikipedia lori itakun agbaye, ilana iwaasu iwa irẹlẹ ni Emmanuel Odumosu, ti gbogbo eeyan mọ si 'Jesu Oyingbo' fi bẹrẹ, ko to wa gbajumọ eto okoowo sise.

Itan igbe aye Jesu Oyingbo yii dun pupọ, to si yẹ ka ri ọgbọn kan abi meji kọ ninu rẹ nitori arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ti eeyan kan ba si se ni oni, ni yoo di itan to ba di ọla.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Jesu Oyingbo:

Emmanuel Olufunmilayọ Odumosu ni orukọ Jesu Oyingbo, Jacob Odumosu ni orukọ baba rẹ, ti baba baba rẹ, Joseph Odumosu si jẹ onisegun ibilẹ ni ilu Ijẹbu Ode.

Ọdun 1915 ni wọn bi Odumosu, o kọ isẹ Gbẹna-gbẹna ta mọ si Kafinta, to si tun sisẹ bii osisẹ lẹka to n ri si pinpin lẹta ati waya lasiko ogun agbaye keji sugbọn idaṣẹsilẹ nla to waye lọdun 1945 lo mu ko fi isẹ naa silẹ.

Emmanuel Odumosu pada si idi isẹ Kafinta, to si nira fun lati ri ọwọ mu lọ sẹnu, ti gbese jijẹ si di baraku fun. Bakan naa ni awọn ẹsun rẹ ti ẹnikan to jẹ lowo fi sun ijọba, ran lọ sẹwọn fun osu mẹfa gbako.

Lẹyin to pada de, ni Odumosu n lọ sawọn ijọ ajihinrere igbalode kaakiri, to si ti ipa ibẹ di aríran ati alálàá, o ni oun ni Olugbala ran wa gba aye la, to si bẹrẹ isẹ iransẹ rẹ nipa sise isin irọlẹ ninu sọọbu rẹ.

Ni igba ti Odumosu bẹrẹ isẹ iransẹ rẹ lọdun 1952, iwaasu kiko ara ẹni nijanu, iwa ọmọluabi ati irẹlẹ lo fi bẹrẹ, ti ijọ rẹ si n gbooro lagbegbe erekusu Eko, Lagos Island, to si ni ki awọn eeyan kọ ọti ati siga mimu pẹlu obinrin kiko silẹ, ti ọmọ ijọ rẹ si to ọgbọn lọdun 1954.

Lasiko yii, Odumosu maa n fi fun awọn alaini, to si tun maa n se koriya fawọn ọmọ ijọ lati maa fi ohun ini wọn silẹ fun itankalẹ ihinrere, ko si pẹ ti ọmọ ijọ tuntun kan fi fi ile rẹ kan silẹ, eyi to wa ni adugbo Ebute Meta nibi ti Odumosu lọ tẹdo si.

Odumosu rọ awọn ọmọ ijọ rẹ lati lọ gba ile si ẹba ijọ naa, ki wọn si fi ile ara wọn ti wọn n gbe silẹ, ki wọn si kede ọrọ ti wọn ni fun ijọ ninu eyi to ti n yọ idamẹwa, bẹẹ lo tun n gba owo ile lọwọ wọn.

Odumosu se amugbooro ijọ rẹ siwaju, to si n fi gbohun-gbohun amohunbugbamu se iwaasu rẹ lẹba ọja Oyingbo, idi si niyi ti wọn se n pe ni Jesu Oyingbo.

Lọna ati gba awọn ọmọ ijọ tuntun mọra, Jesu Oyingbo maa n waasu iwa irẹlẹ ati igbọran, to si tun maa n na awọn ọmọ ijọ tuntun, ti wọn jẹ ọkunrin ni ina ẹgba mẹsan, lati gba wọn wọ agbo ijọ rẹ, ti ọpọ eeyan miran si gbagbọ pe asiri agbara rẹ ni pasan to jogun lati ọwọ baba rẹ naa, eyi to maa fi n na ọmọ ijọ tuntun, ki wọn ma baa sa lọ.

Iroyin miran ni Jesu Oyingbo lo jogun awọn iwe oogun ibilẹ ti baba baba rẹ kọ ko to ku, awọn iwe oogun ibilẹ bii Iwe iwosan, Iwe Egbogi, iwe isọji ati Ewe nla, ti wọn si ni inu awọn iwe naa ni asiri agbara rẹ wa.

A tilẹ gbọ pe ọpọ ọmọ ijọ rẹ lo gba pe lẹyin Jesu Oyingbo, ko tun si Ọlọrun miran mọ, ti iwalaye rẹ nigba naa si jẹ ipadabọ Jesu ni ẹẹkeji. Ọpọ awọn ọmọ ijọ Jesu Oyingbo lo n ta ohun ini wọn, wọn pa awọn mọlẹbi wọn ti lati dara pọ mọ 'Olugbala' wọn.

Lọdun 1959 gan ni Odumosu kede ara rẹ bii Jesu, o se adinku iwaasu rẹ, to si dawọle ọpọ okoowo sise lati fi gbọ bukata Jerusalem tuntun to dawọle.

Lara awọn okoowo to dawọle ni ibudo ounjẹ Jolly makers ati Happy day food canteen, sise burẹdi Deluxe ati Goodluck, ibudo agẹrun ati ile igbalejo, Guest house.

Ni ti ọrọ aje, awọn okoowo yii n mu ki awọn ọmọ ijọ rẹ ri isẹ oojọ se, ti wọn si n gba owo ọya wọn, bi o tilẹ jẹpe ọpọ awọn ọmọ ijọ rẹ ya lọ lọdun 1960 nitori ẹkọ tuntun ti wọn gbọ. Sugbọn eyi ko tu irun kankan lara Jesu Oyingbo nitori o si n tẹsiwaju pẹlu okoowo rẹ ni.

Lara awọn akọle lede oyinbo to wa lara awọn ile to wa ninu ọgba Jesu Oyingbo, to wa ni opopona Emmanuel ladugbo Maryland nilu Eko ni "Alaanu ati alagbara", "baba titi aye", "Ọmọ alade Alaafia" to si tun fi awọn ere Jesu yi wọn ka.

Bakan naa ni ilana isin ti Jesu Oyingbo yii yatọ si ti ilana ẹsin ijọ igbagbọ yoku nitori oun ni agbara ati asẹ ibalopọ lori awọn obinrin to ba wa ninu ijọ rẹ.

Niwọn igba to jẹ pe awaye ku ko si, Jesu Oyingbo dagbere fun aye yii pe o digbose, to si jade laye lọdun 1988 lẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73 years).

Lẹyin ti Jesu Oyingbo papoda tan, ija nla bẹ silẹ lori ogun laarin ọpọ iyawo to bimọ fun ati ogunlọgọ ọmọ to bi, nitori ko se iwe ilana ogun pinpin rẹ silẹ, lasiko yii si ni ọpọ asiri ti ko han sode tẹlẹ, bẹrẹ si tu sita, ti wọn si gbe ara wọn lọ sile ẹjọ fun ọdun gbọọrọ.

Lootọ ni Jesu Oyingbo ti fi aye silẹ sugbọn awọn ohun to gbe ile aye se jẹ manigbagbe, ti yoo wa ni iranti fun igba pipẹ.

Ki ni a o sọ lẹyin ti ọlọjọ ba de fun ẹyin naa?

Ani, nigbakigba too ba fi aye silẹ, jẹ ki idahun naa wa ninu rẹ.

BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI