KORONAFAIRỌỌSI! ÌJỌBA NÀÌJÍRÍÀ ṢETAN LÁTI RA OÒGÙN LỌ́WỌ́ MADAGASCAR - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 11, 2020

KORONAFAIRỌỌSI! ÌJỌBA NÀÌJÍRÍÀ ṢETAN LÁTI RA OÒGÙN LỌ́WỌ́ MADAGASCAR


Ààrẹ Muhammadu Buhari tí sọ pé ìjọba Nàìjíríà tí ṣetan láti ra oògùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Madagascar ń polówó rẹ káàkiri. Oògùn náà ni wọ́n sọ pé ó lè gbógun ti aarun aṣekupani Covid-19 lára ni kíákíá.

Boss Mustapha to jẹ́ akọwe ìjọba àti alaga igbimọ COVID-19 ni Nàìjíríà lo gba ẹnu Ààrẹ Buhari sọ̀rọ̀ lónìí ọjọ́ Aje, Mọnde lásìkò tó ń báwọn oniroyin sọ̀rọ̀ wí pé àwọn tí ṣetan láti dán oògùn náà wò. 

O ni àwọn tí bẹ̀rẹ̀ igbesẹ láti lọ kò àwọn oògùn nítorí pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ, kò too di pé ó dé orí ìgbà àwọn tó ń tà oògùn òyìnbó, ìyẹn Pharmacy. 

AWÍKONKO gbọ pé àwọn orílẹ̀-èdè bíi Equatorial Guinea, Guinea-Bissau, Niger, ati Tanzania ni wọn ti rà oògùn yìí lọ́wọ́ Madagascar.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI