NǸKAN DÉ! ÀLEJÒ TÓ BÁ WỌ KWARA YÓÒ RU IGI OYIN - ÌJỌBA ṢE ÌKÌLỌ̀ ŃLÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 11, 2020

NǸKAN DÉ! ÀLEJÒ TÓ BÁ WỌ KWARA YÓÒ RU IGI OYIN - ÌJỌBA ṢE ÌKÌLỌ̀ ŃLÁA fi kí gbogbo àwọn tó bá ń gbèrò láti wọ ipinlẹ Kwara lásìkò yìí tètè tún ìpinnu àti erongba wọn ṣe lórí àṣẹ tí Gomina AbdulRahman AbdulRazaq gbé kalẹ báyìí.

Ojoojumọ ni aarun koronafairọọsi ń bù rẹkẹ síi káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá n'ipinlẹ náà, tí wọn sì làwọn àlejò tí wọn ń wọlé l'aarun náà fi ń pọ sì.

Lónìí ní Gomina AbdulRazaq tí igbá-kejì rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀ fìdí ẹ múlẹ̀ pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti dẹ́kun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19 náà ni lati fi òfin de ìwọlé-jáde.

Káyọ̀dé Alabi tó tún jẹ́ alága igbimọ COVID-19 nibi tó ti ń báwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ àwọn Haúsá náà sọ̀rọ̀ tún sọ pé àwọn tó ní aarun náà tí wọn ń rí lásìkò yìí ni wón kíi ṣe ọmọ-onilu, bí kò ṣe àwọn àlejò tí wọn ń wọlé wá. 

Nibẹ lo tí rọ àwọn igbimọ náà wí pé kí wọn sọ fún gbogbo àwọn èèyàn wọn níbikíbi tí wọn ba wa, tí wọn ń gbèrò láti wa jókòó síbi tí wọn ba wa nítorí pé kò saaye rárá. 

O ni aarun náà kò mọ olówó àti àlejò, bẹẹ ni kíi hàn lójú àwọn tó bá níi, tó sì jẹ pe bí ẹni tí aarun náà bá wà lára rẹ bá fara ro awon eeyan, ó di dandan kó tán káàkiri. 

Ṣáájú àsìkò yìí, Kọmiṣanna f'ọrọ ìjọba ìbílẹ̀ àti òye jíjẹ n'ipinlẹ náà, Hajia Aisha Ahman-Patigi sọ pé ìjọba kò lè bẹ̀rẹ̀ òfin náà lai jẹ́ pé wọn fi tó àwọn ará ilẹ̀ Haúsá tó wà láàárín wọn létí. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI