Ninu atẹjade ibanikẹdun tí Kọmanda Ọlanrewaju fi ranṣẹ sì AWIKONKO laarọ òní lo tí ṣàlàyé wí pé àdánù ńlá ni ikú Oloye Ọrunṣolu jẹ fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà, pàápàá nínú ẹgbẹ́ Fijilante nipinlẹ Ogun.
Ó ní ibanujẹ ńlá ni ikú Baba náà jẹ nígbà tí ìròyìn náà tẹ òun létí laarọ òní, nítorí pé Aṣiwaju réré táwọn ń tọ ipasẹ rẹ ni, pàápàá nínú ẹsin Isilaamu ni.
Ninu ọrọ rẹ, Kọmanda Ọlanrewaju Adedoyin sọ pé "Pẹ̀lú ibanujẹ là fi ń kẹdun ikú Baba wa, olórí wá, aṣiwaju wá, Oloye Imaamu Sheik Ayinde Liadi Ọrunṣolu to jáde láyé laarọ òní, ọjọ́ Iṣẹgun.
"Ó ṣeni láàánú wí pé àsìkò tí a parí aawẹ Ramadaani Ọlọdọọdun tí ọdún yìí ni Baba wa jáde láyé lẹni ọdún mejidinlọgọrun-un {98}, nítorí pé a kò lè gbàgbé wọn.
"Baba ní Olóògbé Ọrunṣolu jẹ nígbà ayé ẹ, tí a kò sì lè kó ipa rẹ kéré nínú ẹgbẹ́ Fijilante, nítorí pé Baba tó fẹ́ràn àlàáfíà àti irẹpọ ni wọn jẹ nígbà ayé wọn.
"Ẹlẹyinju àánú àti aláàánú àwọn aláìní ni Olóògbé Ọrunṣolu jẹ. Baba yìí tẹle àwọn itọni àti ìlànà ẹsin Isilaamu gẹ́gẹ́ bí ìwé mimọ Kuraani ṣe kọọ, bẹẹ ni wọn sì ń fi ẹ̀kọ́ náà kọ àwọn èèyàn loore-koore.
"Àdúrà mi gẹ́gẹ́ bí ọga VGN nipinlẹ Ogun ni pé kí Ọlọ́run bá wà tẹ wọn sì afẹ́fẹ́ rere. A sì ń fi asiko yii gbàdúrà wí pé kí Ọlọ́run Allah bù òróró ìtura sì ọkàn àwọn mọlẹbi tí gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọn fi silẹ lọ."
No comments:
Post a Comment