WỌN DA ẸJỌ IKÚ FÚN AYỌDEJI ATI ABIỌDUN L'ỌṢUN NÍTORÍ PASITỌ TÍ WỌN JA L'ÓLÈ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 28, 2020

WỌN DA ẸJỌ IKÚ FÚN AYỌDEJI ATI ABIỌDUN L'ỌṢUN NÍTORÍ PASITỌ TÍ WỌN JA L'ÓLÈ


Ìwé mimọ Bíbélì sọ pé 'kí ẹnikẹ́ni má ṣe ẹni aroro mi n' ibi'. Ọ̀rọ̀ náà lo lọ nibamu pẹ̀lú bí ilé ẹjọ́ gíga to fikalẹ silu Ila-Ọrangun, ipinlẹ Ọṣun ṣe pàṣẹ wí pé kí wọn lọọ yẹgi fún gendekunrin méjì kan, Ayọdeji Adeleke àti ọrẹ rẹ, Abiọdun Oyedunmọla. 

Pasitọ kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Afọlabi là gbọ pé Ayọdeji àti Abiọdun kọ́kọ́ digun ja lólè lọ́jọ́ kẹsàn-án oṣù kejìlá ọdún 2015 àti ọjọ́ kejidinlọgbọn oṣù kẹta ọdún 2016.

Gbogbo akitiyan táwọn ọlọ́pàá ṣe láti rí wọn mú nígbà náà là gbọ pé ó já sí pàbó. 

Kò pẹ ni wọn tún lọ digun ja ọkùnrin kan, Bayepade Olubunmi lólè lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹrin ọdún 2016,bẹẹ ni wọn tún digun ja Owonifari Muyideen náà lólè lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù kẹrin ọdún náà. 

Kò ju bí oṣù méjì sí asiko náà là gbọ pé àṣírí àwọn méjèèjì tú síta, t'ọwọ ọlọ́pàá sì tẹ wọn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́. 

Látìgbà náà Láwọn ọlọ́pàá tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ ìwádìí wọn, tí wọn sì kọ́kọ́ fi ojú wọn ba ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ kẹrinlelogun oṣù karùn-ún ọdún tó kọjá. 

Èèyàn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ là gbọ pé wọn jẹrii tako àwọn méjèèjì nílé ẹjọ́, táwọn náà sì jẹwọ pé lóòótọ́ làwọn ń digun jalè. 

Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀, Onidajọ Jide Falọla sọ pé àwọn ẹ̀rí tó wà níwájú òun kọjá afẹnusọ, tí gbogbo rẹ sì fìdí múlẹ̀ pé ògbólógbòó adigunjale wọn. 

Ó ní pàṣẹ ẹ̀wọ̀n gbere fáwọn méjèèjì fún iwa jìbìtì, bẹẹ lo tún pàṣẹ pé kí wọn yẹgi fún wọn lórí ẹ̀sùn idigunjale. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI