Itan ibanujẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Gunners, iyẹn Arsenal fi balẹ l'Ọjọru tii ṣe Wẹside ana n'igba ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City kọna iya gidi fun wọn, ti wọn ko si raaye da nnkankan pada.
Ṣe ni gbogbo awọn ololufẹ wọn kaakiri agbaye n sunkun kiri latigba naa, titi di asiko ta a kọ iroyin yii tan.
Ana Wẹside ni idije liigi ilẹ Gẹẹsi, iyẹn Premiership ti wọn pati lati bi oṣu mẹta le diẹ sẹyin lati dẹkun itankalẹ arun Covid-19, iyẹn koronafairọọsi bẹrẹ ni pẹrẹu.
Goolu mẹta si odo ni idije naa pari si, eyi to mu ki ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti wọn ti n dan ẹnu tẹlẹ wi pe awọn yoo fi oju Manchester City gbolẹ nile wọn pada sile pẹlu itiju nla.
Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ko jẹ iyalẹnu fun ọpọ onwoye
ere bọọlu lagbaye, paapaa idije liigi Premiership.
Ọrọ buruku l'awọn ololufẹ Arsenal kaakiri agbaye n sọ si ọkan lara awọn agbabọọlu to di ọwọ ẹyin mu, iyẹn
David Luiz lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bo ṣe jẹ pe oun gan-an lo ṣokunfa goolu meji ninu mẹta.
Yatọ si eyi, oun naa lo tun gba kaadi jade kuro lori papa, iyẹn kaadi pupa nitori ika nla to ṣe.
Ni ipele kini ifẹsẹwọnsẹ naa ni aṣiṣe David Luiz
ti kọkọ ṣakoba fun Arsena nigba to fara gbe bọọlu to yẹ ko gba danu sọwọ Raheem
Sterling agbabọọlu Manchester city ti toun si kanra gba bọọlu naa sawọn.
Ni abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lo tun ti fa aṣọ
Riyadh Mahrez to jẹ agbabọọlu Mancity ti rẹfiri si fọn fere fun pẹnariti ti o
si tun fun un ni kaadi pupa pe ko jade kuro lori papa.
Luiz kii ṣe ajeji si irufẹ awọn aṣiṣẹ epo n biyọ
bayii to si ti mu ki ọpọlọpọ onwoye bọọlu o maa pe fun ori rẹ.
Pẹlu jijawe olubori yii, O tunmọ si pe ami mẹfa
lo n dabu ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool bayii lojuna ati gba ife ẹyẹ Premiership ti
saa yii.
No comments:
Post a Comment