AWỌN ỌMỌ YAHỌỌ T'ỌWỌ TẸ L'OGUN ATI EKO YOO F'OJU BA ILE-ẸJỌ LAIPẸ - EFCC PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 20, 2020

AWỌN ỌMỌ YAHỌỌ T'ỌWỌ TẸ L'OGUN ATI EKO YOO F'OJU BA ILE-ẸJỌ LAIPẸ - EFCC PARIWO SITA


Ajọ to n gbogun ti ṣiṣẹ owo kumọkumọ, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka t'ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn afurasi ọmọ Yahoo t'ọwọ tẹ laipẹ yii n'ipinlẹ Ogun ati Eko yoo f'oju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii, to si ni ko nii pẹ.

Agbẹnusọ ajọ naa, Ọgbẹni Dele Oyewale lo sọrọ naa sita l'Ọjọru, iyẹn Wẹside to kọja yii.

O ni agbegbe Ọta, ipinlẹ Ogun l'ọwọ ti tẹ Adeṣina Michael, Ayẹni Ẹmiloju, Odenigbo Anthony, Afọlabi Gbenga ati Oyibogbọla David Ṣeun.

Oyewale sọ pe agbegbe Victoria Island lọwọ ti tẹ Onothebor Edmond, Suuru Blessing, Ifẹdapọ Ọpẹyẹmi, Samson Samuel, Oguntade Idowu, Emmanuel Akinyẹmi, Ṣeyi Kazeem, Sulaiman Tọheed, Oduwale Oluwaṣẹsan, Adewoye Oluwaṣẹsan ati Alex Abiọdun.

 
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn kan ni wọn ta ileeṣẹ wọn lolobo lori ẹsun jibiti ati ṣiṣẹ owo kumọkumọ, eyi to loo mu k'awọn lọ ko awọn eeyan yii.

Bẹẹ lo ni mọto bọginni-bọginni loriṣiriṣi l'awọn gba lọwọ wọn lasiko t'awọn lọ ko wọn nile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI