IGBAKEJI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN WỌ GAU, WỌN TUN KO ṢẸKẸṢẸKẸ SII LỌWỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 20, 2020

IGBAKEJI ABẸNUGỌN ILE IGBIMỌ AṢOFIN WỌ GAU, WỌN TUN KO ṢẸKẸṢẸKẸ SII LỌWỌ

Ọjọ manigbagbe l'Ọjọru, iyẹn Wẹside ọsẹ to kọja yii jẹ fun igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Benue, Christopher Adaji lori bi ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede yii, iyẹn EFCC ṣe f'oju rẹ han f'awọn araalu wi pe o lọwọ ninu jibiti owo.

Ki i ṣe bi wọn ṣe f'oju rẹ han f'awọn araalu lo n jẹ fun ọkunrin naa, bi ko ṣe bi wọn tun ṣe ko ṣẹkẹṣẹkẹ sii lọwọ, ti wọn si tun gbe patako ẹṣẹ rẹ sii lọwọ gan an lo n jẹ itiju nla.

Adaji ati agbọpa (Clerk) ile igbimọ aṣofin naa, Torese Agena la gbọ pe wọn jọ lọwọ ninu ẹsun jibiti naa ti ko din ni miliọnu marun-un (N5, 040,950) naira.

Ọjọ naa gan an l'awọn mejeeji tun fi oju ba ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Benue, niwaju Onidajọ S. O. Itodo.

Ẹsun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu owo abẹtẹlẹ ati aṣilo ipo ni wọn fi kan wọn, ti wọn si l'awọn ko jẹbi ẹsun naa. 
Onidajọ Itodo ti wa sun igbẹjọ siwaju ọjọ kẹfa, ọjọ keje ati ọjọ kẹjọ oṣu keje ọdun, to si faaye silẹ f'awọn eeyan naa lati gba beeli ara wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI