ÈPÈ ŃLÁ TÍ MÀMÁ MI ṢẸ LÓ JẸ́ KÍ ÀṢÍRÍ MI TU - EMMANUEL TO FẸẸ FI FỌTO ÌHÒÒHÒ LU SALAWA ABẸNI NI JÌBÌTÌ BU SẸKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 1, 2020

ÈPÈ ŃLÁ TÍ MÀMÁ MI ṢẸ LÓ JẸ́ KÍ ÀṢÍRÍ MI TU - EMMANUEL TO FẸẸ FI FỌTO ÌHÒÒHÒ LU SALAWA ABẸNI NI JÌBÌTÌ BU SẸKUN


Ọdọmọkunrin ẹni ọdún mọkandinlogun kan tó fẹẹ fi fọto ìhòòhò lu gbajumọ olorin waka nnì, Salawa Abẹni ni jìbìtì ni nnkan bí oṣù méjì sẹ́yìn lo tí wá lagọ ọlọ́pàá báyìí, níbi tó ti ń ka boroboro bí ẹyẹ ayekootọ.

Emmanuel Ọladunjoye Olufowokẹ lórúkọ rẹ, ọmọ bíbí ìlú Magboro n'ipinlẹ Ogun ni, bẹẹ lo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yabatech n'ilu Èkó.

Salawa Abẹni lo gbé fọto ìhòòhò rẹ kan sórí ìkànnì ayélujára instagiraamu rẹ, níbi tó ti pariwo síta wí pé kí wọn gba òun lọ́wọ́ ẹni tó fẹẹ fi fọto náà kú òun ni jìbìtì.

Yàtọ̀ sí èyí, a tún gbọ pé Salawa tún mú fọto náà lọ fáwọn ọlọ́pàá wí pé kí wọn ba òun ṣe ìwádìí ẹni náà.

Nígbà náà, Salawa Abẹni sọ pé ẹni náà lo déédéé pé òun lórí fóònù, tó sì ń dunkooko mọ òun pé boun kò bá san owó abẹtẹlẹ, òun (Emmanuel) yóò gbé fọto ìhòòhò rẹ síta láti fi dojú tíì. 


Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ pé lójú ẹsẹ ti Salawa rí fọto náà, lo tí sáré gbé e sórí ìkànnì instagiraamu rẹ láti jẹ káwọn èèyàn mọ pe ẹnikan fẹẹ fi lu òun ni jìbìtì ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Salawa Abẹni kò kọbi ara sì fọto àti ẹni tó fẹẹ luu ni jìbìtì náà mọ, síbẹ̀, àwọn ọlọ́pàá kò dúró láti mọ ẹni tó wà nìdí ìwà náà. 

Nígbà tí àṣírí máa tú ni wọn ríi pé Emmanuel lo wá nibẹ, toun náà sì jẹwọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́, àti bó ṣe gbìyànjú láti má jẹ́ kí àṣírí tú. 

Nínú ọ̀rọ̀ tí Emmanuel sọ nípa ìwà náà, ó ni:

"Mi ó mọ pe àṣírí mi máa padà tú síta. Gbogbo ọgbọ́n ni mo dá láti má jẹ́ kí àṣírí tú. Inú ọgbà ilé-ẹ̀kọ́ mi, Yabatech ni mọ tí rí káàdì tí wọn máa fi sórí fóònù, ìyẹn Memory Card, ti mo sì mu"

"Ìgbà tí mo délé ni mo yẹẹ wo, inú ẹ ní mo ti rí àwọn fọto ìhòòhò Olorin Waka yìí, Salawa Abẹni. Láti fi rí owó, mo lọ sórí ìkànnì instagiraamu Salawa. 

"Ibẹ ni mo ti rí ẹ̀rọ ibanisọrọ ẹ, tí mo sì pe e láti fi fọto náà dunkooko mọ. Mo ní ti ko ba ti fún mi lowo, máa gbé fọto náà síta láti fi yẹyẹ ẹ.

"Mi o mọ pe Salawa lè dá ọgbọ́n tó dá yẹn. Ṣùgbọ́n ní kété tí mo gbọ ìròyìn náà lọ́jọ́ kejì tí mo pé e, mo mọ pe wàhálà ń bọ̀. Èyí ló jẹ́ kí n bá káàdì {Memory Card} náà jẹ lẹsẹkẹsẹ, tí mo sì tún yọ nọ́mbà ẹ̀rọ ibanisọrọ mi dànù, kí àṣírí má bàa tú. 

"Lọ́jọ́ tí mo gbọ ìròyìn náà, màmá mi náà wá níbẹ̀, a sì jọ gbọ ọ ní. Epe ńlá-ńlá ni màmá mi ń ṣẹ fún ẹni tó wà nìdí ìwà burúkú náà, lai mọ pe emi ọmọ rẹ ni." 

Salawa Abẹni nígbà tó ń fi fọto Emmanuel hàn àwọn olólùfẹ́ rẹ lórí ìkànnì ayélujára instagiraamu rẹ lánàá ọjọ́ Àìkú, ìyẹn Sande, ó dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìṣẹ takuntakun tí wọn ṣe láti mú Emmanuel.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI