MI O LE SỌ IYE OWÓ IRANWỌ TAA TÍ GBA L'ORI DIDẸKUN ITANKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI SÍTA, MI Ò MỌ L'ORI - DAPỌ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 5, 2020

MI O LE SỌ IYE OWÓ IRANWỌ TAA TÍ GBA L'ORI DIDẸKUN ITANKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI SÍTA, MI Ò MỌ L'ORI - DAPỌ ABIỌDUN


Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun tí sọ pé òun kò lè sọ iye owó iranwọ t'oun tí gba lọ́wọ́ àwọn ẹlẹyinju àánú fún didẹkun itankalẹ àrùn COVID-19 síta báyìí.

Dapọ Abiọdun lo sọ̀rọ̀ náà lónìí ní ọfiisi rẹ níbi ìpàdé tó ṣe pẹ̀lú àwọn oniroyin nilu Abẹ́òkúta.

Ó ní lóòótọ́ làwọn ẹlẹyinju àánú àtàwọn ileeṣẹ kọ̀ọ̀kan tí ṣe iranlọwọ owó fún ìjọba ipinlẹ Ogun látìgbà tí àrùn náà tí bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kejì ọdún yìí, ṣùgbọ́n tòun kò tíì lè sọ pàtó.

Gómìnà náà tún sọ pé àwọn ṣí akanti sílè ifowopamọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti fi gba àwọn owó yìí wọlé, tí àwọn owó sì ti wọlé bo ṣe yẹ, ṣùgbọ́n tòun kò tíì lè sọ pàtó iye owó tó ti wọlé títí di asiko yii.

Bẹẹ lo tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé àwọn tí na nínú owó náà fún ìtọ́jú àwọn tó ti ko àrùn náà, síbẹ̀, ó lòun kò lè sọ iye owó táwọn tí na lórí ìtọ́jú náà.

Ó lòun kò mọ iye owó náà lórí, ṣùgbọ́n òun yóò bá kọmiṣanna fún eto ìlera ṣe ìpàdé láti mọ iye owó náà, t'oun yóò sì tún pe ìpàdé lórí ẹ láti fi tó gbogbo agbaye létí.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI