GBAJUMỌ ONÍRÒYÌN, BÀBA YORÙBÁ Ṣ'AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ÀÁDỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN FÚN BABA RẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

GBAJUMỌ ONÍRÒYÌN, BÀBA YORÙBÁ Ṣ'AYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ ÀÁDỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN FÚN BABA RẸ̀


"Ẹ bá mi kí bàbá mi, kí ẹ sì bá mi bàa ṣ'ajọyọ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún rẹ lónìí. Bàbá mi Ọ̀wọ́n, Alaaji Sulaiman Akanji BABALỌLA.
"Akanji Ọmọ Ará Oko, Ọmọ Ọṣinle, Ọmọ Lakoole, Ọmọ Abeni Aajo, Ọmọ Ofeku Tóò rẹ, Ọmọ Abimo Laake, Lórílẹ̀ Aké, A bímọ Lóko Lórílẹ̀ Oko, Ọmọ Aritu Gesin, Ọmọ Ootonporo, Ọmọ Are wù, Ọmọ Olodo kan Odò kàn to n ṣàn were, ti o ṣàn wéré ké, O di Eyinkunle Osinle, O dáa bàtà!!!!!"

Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ìwúrí àti oríkì tí gbajugbaja àgbà oniroyin nnì, Ọgbẹni Ismail Abiọdun Babalọla fi ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún bàbà rẹ, Alaaji Sulaiman Akanji Babalọla.


Òní ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí bàbà náà, táwọn èèyàn káàkiri àgbáyé sì ti ń fi àdúrà àlàáfíà àti ẹmi gígùn ranṣẹ sii.


Gbogbo àwa òṣìṣẹ́ ileeṣẹ AWIKONKO náà ń fi tayọtayọ kí Baba kú oriire tí àádọ́rùn-ún ọdún tí wọn pé láyé, bẹẹ là sì ń gbà á ladura pé ẹ̀mí wọn yóò gùn láṣẹ Èdùmàrè. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI