LẸ́YÌN ÌPÀDÉ IKỌKỌ PẸ̀LÚ BUHARI, ỌBASẸKI FI ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC SÍLẸ̀, WỌN TUN NI KÒ TÍÌ SAAYE FÚN NÍNÚ ẸGBẸ́ PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 16, 2020

LẸ́YÌN ÌPÀDÉ IKỌKỌ PẸ̀LÚ BUHARI, ỌBASẸKI FI ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC SÍLẸ̀, WỌN TUN NI KÒ TÍÌ SAAYE FÚN NÍNÚ ẸGBẸ́ PDP


Lónìí ní Gómìnà ipinlẹ Ẹdo, Godwin Ọbasẹki fà káàdì rẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ya, to sì lòun kò ṣe ẹgbẹ́ náà mọ.

Kii ṣe ahesọ mọ wí pé oríṣiríṣi wàhálà ńlá ni Ọbasẹki ń koju nínú ẹgbẹ́ náà, lórí bó ṣe fẹẹ padà lọ s'ipo náà lẹẹkeji, ṣùgbọ́n tí wọn làwọn alágbára nínú ẹgbẹ́ náà kò faaye silẹ fún un.

AWIKONKO gbọ pé lẹ́yìn ìpàdé ikọkọ tí Gómìnà Ọbasẹki ṣe pẹ̀lú Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nilu Abuja ni ọkùnrin náà kéde pé òun kò ṣe ẹgbẹ́ náà mọ. 

Ipada sípò Gómìnà tí wọn ní Ọbasẹki ń wá, èyí tí wọn làwọn alágbára nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò fẹ́ ni wọn loo dá wàhálà silẹ fún un lórí àwọn àṣemáṣe t'oun náà tí ṣe.

Lọ́jọ́ Ẹti, Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni wọn fi òṣèlú hàn Gómìnà Ọbasẹki nínú ẹgbẹ́ nígbà tí wón y'ọwọ rẹ lagbo kúrò nínú àwọn tí yóò díje dupo Gómìnà nipinlẹ náà.

Àwọn mẹ́rin ni igbimọ kan tí wọn yàn láti ṣe ayẹwo fáwọn oludije, èyí tí Ọjọgbọn Jonathan Ayuba lewaju ẹ sọ pé Ọbasẹki kò yege láti díje.

Àwọn mẹ́rin là gbọ pé igbimọ náà yẹwo fínnífínní, àwọn sì ni Pasitọ Ọsagie Ize-Iyamu; Dọkita Pius Odubu, Chris Ogiemwonyi, Osaro Obazee àti Matthew Iduoriyekemwen.

Ní báyìí, ohun tí a gbọ ni pé lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí ń pariwo síta pé àwọn kò fẹ́ Ọbasẹki nínú ẹgbẹ́ náà, tí wọn ń sọ pé àwọn kò fẹ́ kó bá ẹgbẹ́ wọn jẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI