GOMINA AKEREDOLU ṢE BẸBẸ, O PARI FASITI OAUSTECH TI WỌN PATI FUN ỌDUN MẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

GOMINA AKEREDOLU ṢE BẸBẸ, O PARI FASITI OAUSTECH TI WỌN PATI FUN ỌDUN MẸJỌ


Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti sọ pe ko si nnkan to le koko ninu akanṣe iṣẹ idagbasoke t'awọn oloṣelu n pa ti, iyẹn bo ṣe pari fasiti imọ-ẹrọ kan to ti wa ni titi pa lati bi ọdun mẹjọ sẹyin.

Ori ikanni ayelujara ti agbẹyẹfo, iyẹn Twitter ni Gomina Akeredolu ti sọ ọrọ yii di mimọ, to si ni iṣẹ ti pari lori fasiti naa, iyẹn Ondo State University of Science and Technology, (OSUSTECH) to wa n'ilu Okitipupa.

 
Bi iṣẹ naa ṣe pari, Gomina Akeredolu tun kede wi pe oun ti yi orukọ fasiti naa kuro ni eyi to wa tẹlẹ, o loun ti sọ ọ l'orukọ tuntun, iyẹn Olusegun Agagu University of Science and Technology, (OAUSTECH).

Orin idupẹ l'awọn ara ati olugbe ipinlẹ Ondo n kọ bayii, pe eto-ẹkọ to ti d'oku tẹlẹri ti n pada s'ọji bayii.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI