EYI GAN-AN L'AṢIRI IKU TO PA PEPPERITO, GBAJUMỌ SẸNETỌ L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

EYI GAN-AN L'AṢIRI IKU TO PA PEPPERITO, GBAJUMỌ SẸNETỌ L'EKOO


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe ọkan lara awọn gbajugbaja Sẹnetọ n'ilu Eko, Sẹnetọ Sikiru Ọṣinọwọ ti teri gb'aṣọ, koda, ti awọn agbaagba n'idi oṣelu Naijiria, to fi mọ Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti fi lẹta ibanikẹdun ranṣẹ.

Sikiru Ọṣinọwọ to n ṣ'oju ẹkun Lagos East la gbọ pe o jade laye lẹyin aisan rampẹ ni ọsibitu kan ti wọn pe ni First Cardiologist Hospita, to wa n'ilu Eko.

Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi awuyewuye lo ti n lọ kaakiri igboro n'ipa iku to pa gbajumọ oloṣelu naa, ṣugbọn ti AWIKONKO gbọ pe iku rẹ ko ṣẹyin arun Koronafairọọsi to kọluu.
  
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, iyẹn APC n'ilu Eko, Ọnọrebu Ṣẹyẹ Ọladẹjọ f'idi iku naa mulẹ f'awọn oniroyin, bo tilẹ jẹ pe ko ṣalaye nipa aṣiri iku to pa a.

Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 1955 ni wọn bi Oloogbe yii, ọdun 2003 ni wọn dibo yan-an gẹgẹ bi ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko to si ṣ'oju agbegbe Koṣọfẹ.
  
Ọdun 2019 to kọja yii ni wọn fa a kalẹ lati jade du ipo Sẹnetọ, to si gba ipo naa lọwọ Sẹnetọ Gbenga Aṣafa. Ọkan pataki lara awọn ọmọ Aṣiwaju Bọla Tinubu n'idi oṣelu ni Ọṣinọwọ jẹ n'igba aye ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI