IṢẸ NLỌ! ABDULRAZAQ TUN PARI ỌSIBITU OKE-AGODI, L'AWỌN ARAALU BA N FO FUN AYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 20, 2020

IṢẸ NLỌ! ABDULRAZAQ TUN PARI ỌSIBITU OKE-AGODI, L'AWỌN ARAALU BA N FO FUN AYỌGbogbo awọn ara Oke-Agodi ati agbegbe rẹ n'ipinlẹ Kwara ni wọn ti gba ilu, ti wọn si n jo kaakiri ipinlẹ n'igba ti wọn ri i pe iṣẹ ti pari lori ọsibitu t'ijọba tun kọ si agbegbe wọn.

O ti pẹ ti wọn ni iya ilera pipe ti n jẹ awọn eeyan agbegbe yii, ti wọn ko si ri ijọba ti yoo ran wọn lọwọ lati ṣatunṣe ile iwosan naa.

Ninu ileri ati ipinu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ naa lati mu idagbasoke alailẹgbẹ de ba gbogbo ẹka iṣejọba patapata ni wọn ti ṣatunṣe ọsibitu naa fun igbayegbadun awọn araalu lati le jẹ ninu mudunmudun eto iṣejọba awaarawa.

Igbese ijọba yii la gbọ pe o tun n faaye ipese iṣẹ silẹ f'awọn ti ko n'iṣẹ lọwọ lanfaani lati ri iṣẹ ṣe.

Gbogbo awọn ti wọn ri ọsibitu yii ni wọn ti n gbadura agbayipo fun ijọba AbdulaRazaq to mu wọn kuro ninu okunkun bọ sinu imọle ayeraye.

Diẹ re e lara awọn fọto ọsibitu naa fun aridaju:
   


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI