O PARI! NITORI JIBITI, OṢIṢẸ SIFU DIFẸNSI WỌ GAU, L'ADAJỌ BA JU BABA ALI S'ẸWỌN ỌDUN MẸTA GBAKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 18, 2020

O PARI! NITORI JIBITI, OṢIṢẸ SIFU DIFẸNSI WỌ GAU, L'ADAJỌ BA JU BABA ALI S'ẸWỌN ỌDUN MẸTA GBAKO


Ile-ẹjọ giga tilu Gombe ti sọ ọka lara awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi, Zubairu Baba Ali sẹwọn ọdun méta gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.

Ẹsun jibiti ni wọn fi kan Baba Ali l'ọdun 2017.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Muhammed Bashir Muhammad ni Baba Ali gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (N300,000) naira lọwọ rẹ pẹlu ẹtanjẹ lati gbaa s'iṣẹ ninu Sifu Difẹnsi naa.

Wọn ni akanti ile ifowopamọsi ti ẹnikan to n jẹ Iliyasu Yakubu Amana nile ifowopamọ Keystone ni Bashir san owo naa sii.

Latigba naa la gbọ pe Baba Ali ti n fi oni-da-oni fun Bashir, to si jẹ pe ko ri apadabọ owo to san an, eyi lo mu ko lo fọrọ naa to ajọ EFCC leti, ti wọn si bẹrẹ iwadii.

Baba Ali bẹbẹ niwaju ile-ẹjọ pe ki wọn f'oju aanu wo oun nitori t'oun gba ẹbi naa.

N'igba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ A. J. Awak paṣẹ pe ki Baba Ali lọ f'ẹwọn ọdun mẹta gbako gbara, bẹẹ lo tun fi aaye silẹ lati san owo itanran, ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) naira silẹ fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI