IṢẸ-NLỌ! Ẹ TUN WO ỌSIBITU GWARIA T'IJỌBA KWARA ṢẸṢẸ PARI, BẸẸ NI WỌN TUN PARI OPOPONA ỌJA TSARAGI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 16, 2020

IṢẸ-NLỌ! Ẹ TUN WO ỌSIBITU GWARIA T'IJỌBA KWARA ṢẸṢẸ PARI, BẸẸ NI WỌN TUN PARI OPOPONA ỌJA TSARAGI

 
Kii ṣe ahesọ wi pe eto ilera to ti d'oku n'ipinlẹ Kwara lati bi ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti n ji dide bayii, iyẹn labẹ ijọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

Eyi tun ni ọkan lara awọn ọsibitu ijọba kereje-kereje t'ijọba ṣẹṣẹ ṣe atunkọ ẹ pẹlu awọn irinṣẹ igbalode to ba ti ode oni mu, eyi ti wọn ko sibẹ lati maa fi t'ọju awọn alaisan.


Gwaria Primary Health Center to wa ni ijọba ibilẹ Kaiama  lẹ n wo yii. Bo ṣe ri tẹlẹ, ati bo tun ti ṣe dun-un wo bayii.

Yatọ si pe ijọba pari atunṣe rẹ, wọn tun gbe ina agboorun, iyẹn Sola Power sibẹ n'igba ti ko ba si ina mọnamọna, eyi ti iṣẹ ko fi nii duro, bẹẹ ni wọn tun gbe ẹrọ amunawa, iyẹn jẹnẹretọ nla sibẹ pẹluu fun wọn.
 

Bakan naa ninu iroyin to fi ara pẹẹ ni opopona aarin ọja Tsaragi t'ijọba tun ṣẹṣẹ pari, eyi t'awọn agbaṣẹṣe sọ pe opopona naa ti ṣee lo f'awọn araalu

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI