ÌWÉ ÌRÒYÌN AMẸBỌ BALẸ SÓRÍ IGBÁ LỌ́NÀ ARA Ọ̀TỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 13, 2020

ÌWÉ ÌRÒYÌN AMẸBỌ BALẸ SÓRÍ IGBÁ LỌ́NÀ ARA Ọ̀TỌ̀Gbajugbaja ìròyìn orí ìkànnì ayélujára nnì, Amẹbọ tí di ìwé báyìí, tó sì ti di ohun tí wọn ń pè ní ìwé ìròyìn, táwọn èèyàn sì ti ń retí láti gba a kà.

Aláṣẹ àti oludasilẹ ìwé ìròyìn AMẸBỌ náà, Kọmureedi Ṣolankẹ Ayọmideji Taiwo lo gbé ìròyìn náà síta lórí ìkànnì ayélujára abanidọrẹ tí Fesibuuku rẹ laipẹ yìí wí pé ìwé náà tí jáde síta, tó sì kú díẹ̀ kò de ori igbá. 


Odu ni ìròyìn Amẹbọ, ó kii ṣaimọ foloko, pàápàá fáwọn to bá nifẹ láti máa ka ìròyìn lórí ayélujára káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, pàápàá lagbaye. 


Ọkàn ó jọkan làwọn ìròyìn tó wà nínú ìwé ìròyìn náà. Ọjọ́ Ajé, Mọnde ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí là gbọ pé yóò jáde sórí atẹ ìwé ìròyìn káàkiri Nàìjíríà fáwọn èèyàn láti ra. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI