AYE MA LE O! WỌN TUN FIPA BA AKẸKỌỌ MI-IN LAṢEPỌ LAYIKA ṢỌỌṢI TO FI KU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 14, 2020

AYE MA LE O! WỌN TUN FIPA BA AKẸKỌỌ MI-IN LAṢEPỌ LAYIKA ṢỌỌṢI TO FI KU

Kayeefi nla niṣẹlẹ naa tun jẹ nigba ti wọn tun gbọ pe awọn gendekunrin kan tẹnikẹni ko tii mọ d'asiko taa kọ iroyin yii tan tun fipa ba akẹkọọ kan, Grace  Oshiagwu laṣepọ, ti wọn si tun ṣaa pa.

Adugbo kan ti wọn pe ni Idi-Ori to wa n'ijọba ibilẹ Akinyẹle, ilu Ibadan n'ipinlẹ Ọyọ n'iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Abamẹta, Satide ana.

Ohun ti a gbọ ni pe nnkan bi aago mẹta ọsan n'iṣẹlẹ abami naa waye, iyẹn nigba ti wọn l'awọn ara adugbo naa ri Grace, ọmọ ọdun mọkanlelogun ninu agbara ẹjẹ, nibi ti wọn ṣaa pa sii.

Awọn olukẹdun 
AWIKONKO gbọ pe ipele kinni ni Grace wa nile ẹkọ gbogboniṣe ti Oke-Ogun, ipinlẹ Ọyọ. 

Ayika ṣọọṣi CAC ti baba Grace ti jẹ oluṣọ aguntan ni wọn ti fipa ba a laṣepọ, nibẹ si ni wọn pa a danu sii lẹyin ibasun gbigbona.

N'igba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọgbẹni Olugbenga Fadeyi to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ sọ pe kayeefi n'iṣẹlẹ naa jẹ f'oun nigba toun gbọ sii, to si l'awọn ti bẹrẹ iwadii nipa awọn to pa Grace.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI