IYAWO GOMINA KWARA ṢE IRANLỌWỌ NLA FUN IYAALE ILE TO BI IBẸTA N'ILỌRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 26, 2020

IYAWO GOMINA KWARA ṢE IRANLỌWỌ NLA FUN IYAALE ILE TO BI IBẸTA N'ILỌRIN

Iyawo Gomina ipinlẹ Kwara, Arabinrin Olufọlakẹ AbdulRazaq l'Ọjọbọ Tọside ana fun idile Adebiyi l'awọn nnkan iranwọ lati fi ṣe itọju awọn ọmọ mẹta ti wọn ṣẹṣẹ bi ati iya awọn ọmọ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ Mọnde to kọja yii ni Arabinrin Adebiyi bi ibẹta nipasẹ iṣẹ-abẹ, eyi to waye ni ọsibitu ijọba nilu Ọffa.

AWIKONKO gbọ pe asiko ko ti i to lati bi awọn ọmọ naa, ṣugbọn nitori awọn aisan to wa lara iya wọn lo jẹ ki wọn pinuu lati ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Lẹyin iṣẹ abẹ naa la gbọ pe wọn ti bẹrẹ si i tọju awọn ọmọ yii pẹlu iya wọn toun ti ara rẹ ko ti i ya.

Bi ọrọ naa ṣe ta si iyawo gomina leti lo ti paṣẹ pe ki awọn amugbalẹgbẹ rẹ lọ ṣe iranwọ to yẹ fun un.

Ọsibitu ijọba to wa ni Ọffa la gbọ pe iya awọn ọmọ naa wa bayii, nibi to ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI