IKU AJIMỌBI! GOMINA ABDULRAZAQ FI LẸTA IBANIKẸDUN RANṢẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 26, 2020

IKU AJIMỌBI! GOMINA ABDULRAZAQ FI LẸTA IBANIKẸDUN RANṢẸGomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara naa ti pẹlu awọn gomina to fi lẹta ibanikẹdun iku gomina ana n'ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ranṣẹ si idile rẹ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ.

O ni ibanujẹ nla ni iku Ajimọbi jẹ fun awọn ara Ọyọ, paapaa orilẹ-ede Naijiria, to si n gbadura pe ki Allah tẹ ẹ si afẹfẹ rere.


“Iku Sẹnetọ Isiaka Abiọla Ajimọbi jẹ adanu nla fun idile ẹ, ijọba APC ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ, paapaa orilẹ-ede Naijiria. Akikanju eeyan ni Ajimọbi, ẹni to n gbe orukọ Naijiria larugẹ, to si fi ara jin lati sin awọn eeyan."

O ni ọrẹ oun bi mọlẹbi oun ni Sẹnetọ Ajimọbi, to si sunmọ idile oun daadaa, to si loun ko le gbagbe ẹ titi lai nitori pe oludamọran gidi ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI