KO SẸNI TO LE GBA NÀÌJÍRÍÀ KÚRÒ LỌ́WỌ́ FULANI TITI LÁÍ, ÀWỌN FIJILANTE WA YÓÒ BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ LAIPẸ - MIYETTI ALLAH PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 6, 2020

KO SẸNI TO LE GBA NÀÌJÍRÍÀ KÚRÒ LỌ́WỌ́ FULANI TITI LÁÍ, ÀWỌN FIJILANTE WA YÓÒ BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ LAIPẸ - MIYETTI ALLAH PARIWO SITA


Aarẹ ẹgbẹ́ Miyetti Allah Kautal Hore, Bello Abdullahi Bodejo tí sọ pé gbogbo nnkan ti yoo ba gba láti jẹ ki awon ẹ̀yà Fulani máa ṣe ìṣàkóso orílẹ̀-èdè Nàìjíríà títí lai làwọn yóò fún un, àti pé kò sẹni tó lè gbà ìṣàkóso kúrò lọ́wọ́ wọn. 

Miyetti Allah lo sọ̀rọ̀ náà laipẹ yìí, to sì ni gbogbo eto lo tí parí báyìí kí eto ààbò Fulani bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu káàkiri Nàìjíríà, bẹẹ lo ni kò sẹni náà tó lè dá àwọn dúró. 

Ọkùnrin náà sọ pé ẹ̀yà Fulani lo ni Nàìjíríà, nítorí náà lo ṣe jẹ́ pé aṣegbe ni gbogbo nnkan táwọn bá ṣe. 

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Ẹgbẹ́ mi, Miyetti Allah Kautal Hore, a ń gbìyànjú láti dá eto ààbò tiwa silẹ. 

"Agbeyẹwo tá ń ṣe ní láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún. Nígbà tí táwọn Yorùbá jẹ Amọtẹkun, àwa náà yóò fi orúkọ tiwa síta laipẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé 'Fijilante Miyetti Allah' là máa pèé" 

Ó sọ pé àrùn aṣekupani tí koronafairọọsi lo dá wọn dúró láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ nítorí tí wọn sọ pé ká má sunmọ ara wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé "kò sí nnkan tó kàn wá pẹ̀lú koronafairọọsi tí wọn ń pariwo". 

"A máa ṣe ìpàdé laipẹ, a sì máa fi tó gbogbo ayé létí. Àwọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún là máa fi bẹ̀rẹ̀. Gbogbo Nàìjíríà ni wọn máa wà nítorí pé kò sí àgbègbè kan ni Nàìjíríà yìí tí ẹ kò níí bá Fulani."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI