AWOKỌṢE RERE NI PA ỌLỌ́RUNNÍṢỌLÁ - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 7, 2020

AWOKỌṢE RERE NI PA ỌLỌ́RUNNÍṢỌLÁ - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tí ṣàpèjúwe Olóyè Peter Ọlọrunniṣọla gẹ́gẹ́ bí awọkọṣe tí ipa tó ti ko láwùjọ, pàápàá ẹka eto ìdájọ́ kò ṣeé fọwọ́ rọ sẹ́yìn. 

Gómìnà AbdulRazaq nínú ọ̀rọ̀ tó fi kí Olóyè Peter Ọlọrunniṣọla fún tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rin ọdún rẹ tó wáyé lónìí lo tí fi imọriri rẹ hàn síta, tó sì gbàdúrà ẹmi gígùn àti àlàáfíà fun-un. 

Ó ní "Pa Ọlọrunniṣọla jẹ akíkanjú àti awokọṣe fáwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn. Ó ti kó ipa tó jọju lẹka eto ìdájọ́ lórílẹ-èdè Nàìjíríà, pàápàá nipinlẹ Kwara. Yàtọ̀ sí pé ó ti sin ipinlẹ naa loriṣiriṣi ẹka, tó fi mọ adajọ àgbà ati kọmiṣanna fún eto ìdájọ́, ó tún jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó ṣeé tọ́ka sí."

Bakan naa lo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run túbọ̀ fún bàbá náà ni ẹmi gígùn àti àlàáfíà to péye. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI