Lonii ni ijọba ipinlẹ Kwara tun f'idi rẹ mulẹ wi pe ko tii to asiko t'awọn alaga kansu at'awọn igbimọ kaakiri ipinlẹ naa yoo pada sipo wọn, to si l'ohun fi oṣu mẹfa gbako kun idaduro wọn.
Idaduro yii ko ṣẹyin iwa jibiti ati ajẹbanu ti wọn loo waye kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara.
Ninu atẹjade ti akọwe gomina, Rafiu Ajakaye fi sita laarọ oni, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ la ti gbọ pe idaruo naa ti ile igbimọ aṣofin bu ọwọ luṣi n tẹsiwaju, ati pe oṣu mẹfa gbako ni yoo fi tẹsiwaju.
AWIKONKO gbọ pe iwa jibiti to waye kaakiri awọn ijọba ibilẹ naa ni ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu lorilẹ-ede yii, iyẹn EFCC ti bẹrẹ iwadii, ti wọn si ni iwadii naa ko tii pari.
No comments:
Post a Comment