SULTAN T'ILU ṢOKOTO SỌRỌ BURUKU S'IJỌBA BUHARI AT'AWỌN ELETO AABO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 18, 2020

SULTAN T'ILU ṢOKOTO SỌRỌ BURUKU S'IJỌBA BUHARI AT'AWỌN ELETO AABO


Sultan tilu Ṣokoto, Alaaji Sa'ad Abubakar ti sọ pe airoorun sun lo yẹ ki ọrọ eto aabo orilẹ-ede yii jẹ fun ijọba Najiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni ohun to n kan gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii lominu ni bi iwa ipaniyan, ijinigbẹ, idanasunle ṣe n lọ kaakiri, ti ijọba ko si wa nnkan ṣe sii.

Sultan tilu Ṣokoto to tun jẹ Aarẹ apapọ fun Jamaatu Nasril Islam lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita.

O ni bi ipaniyan ṣe n lọ kaakiri orilẹ-ede yii, paapaa l'oke-ọya, iyẹn ilẹ Hausa yẹ ko jẹ nnkan ibanujẹ fun ijọba Naijiria, ti ko si yẹ ki maa ri oorun sun pẹlu bi nnkan ṣe n lọ lasiko yii.

Ninu atẹjade naa ti akọwe rẹ, Ọmọwe Khalid Abubakar Aliyu bu ọwọ lu lo tun si rawọ ẹbẹ si gbogbo ileeṣẹ eleto aabo kaakiri Naijiria tubọ fi agbara kun agbara wọn lati gbogun ti aisi eto aabo to peye f'awọn eeyan.
O ni "Bi ipaniyan ṣe n lọ kaakiri yii, ti wọn n dana sun ile, ti wọn n pa nnkan ọsin n'ipinlẹ Borno, Katsina, Sokoto, Zamfara, Niger states at'awọn ipinlẹ bii Adamawa, Kaduna ati Taraba yẹ ko fun ijọba at'awọn ti ọrọ kan lapapọ ati ipinlẹ ni airi oorun sun.

“Lasiko yii, o yẹ ki awọn igbesẹ ati ojuṣe kọọkan ti bẹrẹ lati ọdọ ijọba to wa nita lonii lati tete dẹkun ẹ, ko yẹ ko jẹ ọrọ ẹnu lasan ni wọn yoo maa fi kilọ f'awọn oniṣẹ ibi yii."

Sulatan ni ki lo de ti ijọba ko faaye silẹ f'awọn eeyan lati sọrọ ẹnu wọn jade, k'ijọba le gbe igbesẹ lee lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI